Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ko din leeyan mẹta ti ọkọ ajagbe tẹ pa niluu Ọwẹna, eyi to wa loju ọna marosẹ Akurẹ si Ileṣa lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn obinrin mẹta kan ni ọkọ ajagbe kọkọ gba nibi ti wọn ti n ra ọja laaarọ ọjọ naa, lọgan lẹnikan ti ku ninu wọn, ti ẹni keji si pada ku loju ọna nigba ti wọn n gbe e lọ si ọsibitu. Ẹni kẹta wọn nikan lori ko yọ to si wa ni ileewosan, níbi to ti n gba itọju lọwọ.
Ko ju wakati diẹ lọ lẹyin eyi ni ijamba mi-in tun ṣẹlẹ ni Ọwẹna-Owode, nitosi ibi iṣẹlẹ akọkọ. Ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Toheeb la gbọ pe ọkọ ajagbe mi-in tun tẹ pa lasiko to wa lori ọkada ti oun funra rẹ n gun.
Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun jẹ ka ri i gbọ pe epo ni Toheeb lọọ ta lọja Ọwẹna lọjọ naa, bo ṣe taja rẹ tan lo di ofifo kẹẹgi epo rẹ sẹyin ọkada, to si n pada sile.
Ọrun kẹẹgi epo to di sẹyin lo ṣeesi ha sara ọkọ ajagbe kan lasiko to fẹẹ sare ya ọkọ naa silẹ, leyii to mu ko ṣubu sabẹ tirela ọhun, tiyẹn si tẹ ẹ pa loju-ẹsẹ.
Ọrọ iku awọn mẹtẹẹta to waye laarin wakati díẹ̀ sira wọn lo bi awọn ọdọ kan lagbegbe ọhun ninu ti wọn fi bẹrẹ si i fẹhonu han, wọn dana si aarin oju ọna marosẹ naa, wọn si di i pa patapata fun ọpọlọpọ wakati ki awọn agbofinro too pada waa tu wọn ka.