Ọkọ pa akẹkọọ ileewe girama to fẹẹ sọda titi l’Ọdẹda

Adefunkẹ Adebiyi,  Abẹokuta

Ọkan ninu awọn akẹkọọ ileewe girama Ẹgba Ọdẹda Secondary School, Ọdẹda nipinlẹ Ogun, padanu ẹmi rẹ lọsan-an Ọjọbọ, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa yii, lẹyin to ṣiwọ nileewe, to si fẹẹ sọda titi pẹlu awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ yooku, nitosi Abule Beni, Oko Oloshi, loju ọna marosẹ Abẹokuta s’Ibadan.

Alaye ti Babatunde Akinbiyi ti i ṣe Alukoro TRACE, ṣe nipa iṣẹlẹ yii ni pe obinrin lọmọ ti mọto pa naa. O ni ni nnkan bii aago mẹta ọsan ku iṣẹju mẹẹẹdogun niṣẹlẹ ọhun waye.

Akinbiyi sọ ọ di mimọ pe ki i ṣe ọmọ to doloogbe yii nikan lo fẹẹ sọda sodi keji ọna, o loun atawọn ẹgbẹ rẹ yooku ti wọn jọ jade nileewe lọjọ naa ni. O ni ṣugbọn mọto ti ẹnikẹni ko le ṣapejuwe rẹ naa kọ lu ọmọ to doloogbe yii, ko si duro, bo ṣe gba a danu ti ọmọ doloogbe naa lo ti sa lọ patapata.

Alukoro TRACE sọ pe mọṣuari ọsibitu jẹnẹra lawọn gbe oku ọmọbinrin naa lọ.

O ba awọn ẹbi ọmọ to padanu ẹmi rẹ yii kẹdun, o si rọ awọn akẹkọọ pe ki wọn tubọ maa ṣọra gidi bi wọn ba fẹẹ sọda titi, nitori awọn oniwakuwa awakọ bii eyi ti ẹnikẹni ko le da mọ pọ loju popo.

Leave a Reply