Lẹyin abẹwo awọn gomina, Mimiko pada sinu ẹgbẹ PDP lẹẹkẹta

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lati bii ọsẹ meji sẹyin ni awuyewuye tí n gba ilu kan pe gomina tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Dokita Olusẹgun Mimiko, tun fẹẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP to ti binu kuro lọdun kan sẹyin.

Iroyin naa kọkọ fẹẹ jọ bii ahesọ lasan loju awọn eeyan kan, sugbon ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu awọn to mọ agba oloṣelu ọmọ bibi ilu Ondo ọhun bii ẹni mowo pe loootọ lo ti n gbe igbesẹ labẹnu lori bo ṣe fẹẹ pada sinu ẹgbẹ Ọlọnburẹla.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọlẹyin Mimiko tẹlẹ ni pupọ awọn to jẹ abẹnugan ninu ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ondo lọwọlọwọ, sibẹ ọpọlọpọ wọn ni wọn ko fẹ ki eegun rẹ tun sẹ mọ laarin wọn, koda kiakia lọkan ninu wọn ti figbe ta, to si ni ile-ẹjọ ni yoo bawọn yanju rẹ bi ọkunrin ti wọn n pe ni Iroko naa ba fi dabaa ati pada sọdọ awọn ninu ẹgbẹ PDP.

Iroyin to ti wa nilẹ tẹlẹ yii ni ko jẹ ko fi bẹẹ ya awọn eeyan lẹnu nigba ti wọn deedee ri awọn Gomina mẹrin lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP, Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Nysom Wike láti ipinlẹ Rivers, Okezie Ikpeazu ti Abia ati Gomina ipinlẹ Sokoto to tun jẹ alaga gomina ẹgbẹ oṣelu PDP, Alaaji Aminu Tambuwa, ti wọn waa ba Mimiko lalejo nile rẹ to wa niluu Ondo lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Papakọ ofurufu to wa l’Akurẹ lawọn gomina ọhun kọkọ ti pade laaarọ ọjọ naa ki wọn too jọ kọwọọrin lọ siluu Ondo lọdọ Iroko.

Ohun to jẹ kayeefi fawọn oniroyin atawọn to wa nibẹ lọjọ naa ni pe, yatọ sawọn alatilẹyin Mimiko bii, Clement Faboyede, ẹni to ṣẹṣẹ kuro nipo alaga ẹgbẹ laipẹ yii, Agboọla Ajayi, igbakeji gomina tẹlẹ ati oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party lasiko eto idibo ọdun to kọja, Gboye Adegbenro to ti figba kan jẹ kọmiṣanna feto iṣẹ ode lasiko iṣejọba Mimiko, olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina nigba naa, Dokita Kọla Akinmujimi, Jumọkẹ Akindele, to jẹ abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo tẹlẹ atawọn mi-in, ko si eyikeyii to yọju ninu awọn ọmọ ẹgbẹ to wa nibẹ lọwọlọwọ.

Lẹyin tawọn gomina mẹrẹẹrin ọhun pari ipade idakọnkọ ti wọn kọkọ ba Mimiko ṣe lẹyin ti wọn gunlẹ sile rẹ ni wọn too jade lati ba awọn eeyan to ti n reti wọn tẹlẹ sọrọ.

Ninu ọrọ soki ti Tambuwa sọ, o ni isọri awọn eeyan meji lo wa ni Naijiria lọwọlọwọ, o ni awọn ọmọ ẹgbẹ APC loun fi we isọri akọkọ, eyi ni awọn tinu wọn n dun, ti wọn si n gba yun-un bii eera inu ṣuga, nigba ti isọri awọn eeyan keji jẹ awọn araalu tinu wọn ko dun latari iya ajẹpalori ti wọn fi n jẹ wọn.

O ni gbogbo eyi lawọn ro papọ ti awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP fi pinnu ati gbe igbesẹ lori idande ati irapada awọn eeyan kuro labẹ ijọba to n mu wọn sin lọwọ.

Tambuwa ni awọn waa ba Mimiko  ko le pada sọdọ awọn nitori pe, ka rin ká pọ, yiyẹ ni i yẹ ni.

Nigba to n kín ọrọ alaga wọn lẹyin, Gomina Nysom Wike ni ajọmọ gbogbo awọn gomina ẹgbẹ PDP ni igbesẹ ti awọn n gbe lati yọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii kuro loko ẹru ti ẹgbẹ APC ju wọn si, o ni idi ree tawọn ṣe wa sọdọ Mimiko lati rọ ọ ko le pada wa sinu ẹgbẹ awọn, ki erongba rere ti awọn n gbero rẹ baa le di mimusẹ.

Ṣugbọn nigba ti Mimiko funra rẹ n bawọn oniroyin sọrọ lẹyin tawọn alejo rẹ tí lọ tan, o ni ko sirọ ninu gbogbo ohun tawọn to waa ba oun lalejo naa sọ, bo tilẹ jẹ pe oun ko ti i le sọ ni pato boya oun gba ohun ti wọn sọ tabi bẹẹ kọ.

O ni kawọn oniroyin si foun laaye diẹ na nitori pe oun si fẹẹ ṣepade bonkẹlẹ pẹlu awọn alatilẹyin oun, ki oun too mọ esi toun fẹẹ fun wọn.

Lẹyin wakati mẹta to ti pade awọn gomina ni Alaga ẹgbẹ oṣelu ZLP, Họnọrebu Joseph Akinlaja sọ pe lẹyin ipade awọn alẹnulọrọ kaakiri ijọba ibilẹ mejidinlogun, tawọn ṣe nile Dokita Oluṣẹgun Mimiko lawọn ti fẹnu ko lati pada sinu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Akinlaja ni lẹyin ipade tawọn ṣe, ninu eyi ti igbakeji gomina Ondo tẹlẹ, Ajayi Agboọla, ẹni to mu bii igbakeji rẹ lasiko idibo, Gboye Adegbenro, olori ileegbimọ aṣofin Ondo tẹlẹ, Jumọkẹ Akindele.

Ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy (AD) ni Mimiko laarin ọdun 1999 si 2003, koda, oun ni kọmisanna feto ilera nipinlẹ Ondo lasiko iṣejọba Oloogbe Adebayọ Adefarati, ṣugbọn ni kete ti ẹgbẹ ọhun tun fun ọga rẹ ni tikẹẹti ati dije lẹẹkeji lo binu kuro ninu ẹgbẹ naa, to si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ PDP.

Mimiko ni Dokita Olusẹgun Agagu yan gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ Ondo ni kete to jawe olubori ninu eto idibo gomina ọdun 2003, ṣe ni wọn si jọ ṣejọba ọhun titi di ọdun 2007 tí eto idibo mi-in tun fẹẹ waye.

Ọrọ idibo yii loun ati Agagu tun fi pín gaari nigba ti wọn tun fun un laaye lati dije dupo gomina lẹẹkeji, ibinu eyi lo fi lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Labour ti Dan Nwayawu da silẹ, nibẹ lo ti gbe apoti, to si wọle gẹgẹ bii gomina lọdun 2007, bo tilẹ jẹ pe inu oṣu keji, ọdun 2008, lo too gori aleefa lẹyin idajọ ile-ẹjọ.

Igba ti saa kejì rẹ ku dẹdẹ ko pari lọdun 2015 lo tun kẹru rẹ pada sinu ẹgbẹ PDP to ti kuro bo tilẹ jẹ pe igbesẹ naa ko dun mọ awọn to ba ninu ẹgbẹ ninu lọdun naa lọhun-un.

Igbesẹ bo ṣe waa darapọ mọ wọn lọsan-an gangan, to si tun fipa fa Eyitayọ Jẹgẹdẹ to jẹ ọkan ninu awọn alatilẹyin rẹ nigba naa le wọn lori gẹgẹ bii oludije sipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2006 bí awọn eeyan kan ninu pupọ.

Ọrọ yii pada di tile-ẹjọ tile-ẹjọ leyii to ṣokunfa bi Jẹgẹdẹ ṣe fidi-rẹmi, ti Arakunrin Rotimi Akeredolu to dije labẹ asia ẹgbẹ APC si wọle fun igba akọkọ.

Ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ PDP ni inu wọn ko yọ si Mimiko titi ti eto idibo mi-in tun fi bẹrẹ lọdun to kọja (2020).

Bo tilẹ jẹ pe aayo Mimiko nigba kan ri, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, lẹgbẹ tun fun ni tikẹẹti lẹyin to jawe olubori ninu eto idibo abẹle lati koju Akeredolu ti ẹgbẹ APC to tun fẹẹ dupo lẹẹkeji, Mimiko ko fi bo rara pe inu oun ko dun si i rara, ati pe oun ko ṣetan lati ṣatilẹyin fun un ko le yege ninu eto idibo naa.

Lai fi ti ẹbẹ ti wọn bẹ ẹ pe ko dariji Jẹgẹdẹ ṣe, ẹgbẹ oṣelu mi-in, eyi to pe ni Zenith Labour Party lo lọọ da silẹ nigba ti eto idibo ku bii oṣu mẹrin pere, to si gba Agboọla Ajayi wọle gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ naa.

Ọrọ yii ko ti i tan ninu pupọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ipinlẹ Ondo titi di ba a ṣe n sọrọ yii pẹlu bi wọn ṣe n fẹsun kan Mimiko pe oun lo yi Jẹgẹdẹ lagbo da sina ti ko fi rọwọ mu ninu eto idibo naa lẹẹkeji.

Leave a Reply