Ọlawale Ajao, Ibadan Tẹslim kilọ fun Makinde: To o ba gbidanwo lati yọ igbakeji rẹ, wahala nla ni fun ọ Ikilọ ti lọ sọdọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pe to ba dan gbogbo igbiyanju ẹ lati yọ Igbakeji rẹ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, to ti darapọ mọ ẹgbẹ APC bayii nipo, yoo yọ silẹ fun un. Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Teslim Fọlarin lo ṣe ikilọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, latẹnu Oludamọran rẹ lori eto iroyin, YSO Adeniyi. Fọlarin ni gbogbo igbesẹ awọn aṣofin ti Ṣeyi Makinde ti pin owo fun ti wọn fẹẹ yọ Ọlaniyan ko ni i ṣee ṣe rara nitori ida meji ninu mẹta awọn ọmọ igbimọ ni wọn gbọdọ fọwọ si iyọnipo naa. O ni lara awọn aṣofin naa ti wọn ṣi ni ẹri ọkan, atawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti wọn dibo yan ọkunrin naa lati lo ọdun mẹrin nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina ni yoo lodi si igbesẹ gomina yii. O ni iyansipo gomina yii ṣi wa labẹ ofin, ti ko si si ohunkohun to le ṣi i nidii titi di ọjọ klọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun to n bọ. Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to pari yii, ni awọn ọmọ ileegbimọ aṣọfin ipinlẹ Ọyọ bẹrẹ igbesẹ lati yọ Igbakeji gomina wọn naa, Ẹnjinnia Rafiu Ọlaniyan nipo. Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o hu awọn iwa ti ko tọ, o ṣe awọn owo kan to wa ni ikapa rẹ mọkumọku, aṣilo ipo to wa gẹgẹ bii igbakeji gomina, bẹẹ ni wọn tun sọ pe o fi ọfiisi ati iṣẹ to yẹ ko maa ṣe gẹgẹ bii igbakeji gomina silẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn aṣofin mẹrinlelogun ni wọn ti fọwọ si iyọnipo rẹ latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Ọlawale Ajao, Ibadan
Tẹslim kilọ fun Makinde: To o ba gbidanwo lati yọ igbakeji rẹ, wahala nla ni fun ọ
Ikilọ ti lọ sọdọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pe to ba dan gbogbo igbiyanju ẹ lati yọ Igbakeji rẹ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, to ti darapọ mọ ẹgbẹ APC bayii nipo, yoo yọ silẹ fun un.
Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Teslim Fọlarin lo ṣe ikilọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, latẹnu Oludamọran rẹ lori eto iroyin, YSO Adeniyi.
Fọlarin ni gbogbo igbesẹ awọn aṣofin ti Ṣeyi Makinde ti pin owo fun ti wọn fẹẹ yọ Ọlaniyan ko ni i ṣee ṣe rara nitori ida meji ninu mẹta awọn ọmọ igbimọ ni wọn gbọdọ fọwọ si iyọnipo naa.
O ni lara awọn aṣofin naa ti wọn ṣi ni ẹri ọkan, atawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti wọn dibo yan ọkunrin naa lati lo ọdun mẹrin nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina ni yoo lodi si igbesẹ gomina yii.
O ni iyansipo gomina yii ṣi wa labẹ ofin, ti ko si si ohunkohun to le ṣi i nidii titi di ọjọ klọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun to n bọ.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to pari yii, ni awọn ọmọ ileegbimọ aṣọfin ipinlẹ Ọyọ bẹrẹ igbesẹ lati yọ Igbakeji gomina wọn naa, Ẹnjinnia Rafiu Ọlaniyan nipo.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o hu awọn iwa ti ko tọ, o ṣe awọn owo kan to wa ni ikapa rẹ mọkumọku, aṣilo ipo to wa gẹgẹ bii igbakeji gomina, bẹẹ ni wọn tun sọ pe o fi ọfiisi ati iṣẹ to yẹ ko maa ṣe gẹgẹ bii igbakeji gomina silẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn aṣofin mẹrinlelogun ni wọn ti fọwọ si iyọnipo rẹ latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Leave a Reply