Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn ole meji kan ku ni lairo tẹlẹ. Ibọn lawọn ọlọpaa fi pa wọn, ni Interchange, Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, nigba ti wọn n pitu ọwọ wọn lọwọ, tọrọ waa dija laarin ole ati ọlọpaa.
Alẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an ọjọ Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, ni ipe kan de ọdọ DPO teṣan Ṣagamu, pe idigunjale kan n lọ lọwọ ni Ṣagamu Interchange, ati pe gbogbo awọn eeyan ti awọn ole naa n da lọna ni wọn ti ṣe leṣe buruku, ti wọn ṣa wọn ladaa.
CSP Okiki Agunbiade, DPO ẹkun naa ko awọn ọmọọṣẹ rẹ sodi, wọn gba Interchange lọ.
Bi wọn ṣe debẹ ni wọn ba awọn ole yii ti wọn n kọ lu ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Agba Enoch, bo ṣe di pe awọn ọlọpaa kọju ija si wọn niyẹn, lawọn naa ba n da a pada.
Lẹyin ibọn laulau naa, ole meji ṣubu loju ija, wọn ba ogun ọlọpaa lọ, awọn yooku naa fara gbọta, wọn gbe ọta ibọn sa lọ.
Ọkunrin kan ti wọn ti ṣa ladaa yanna-yanna, Adekunle Adewale, lawọn ọlọpaa sare gbe lọ sileewosan gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun ṣe wi, o si wa nibẹ to n gbatọju lọwọ.
Awọn nnkan tawọn ọlọpaa gba lọwọ wọn ni foonu mẹta, ibọn kan, irinṣẹ ti wọn fi n gẹrun, kaadi ATM mẹta ati ada kan ti ẹjẹ ti rẹ gidi.
CP Edward Ajogun, Ọga ọlọpaa Ogun, gboṣuba fawọn ọlọpaa to ṣiṣẹ naa. O ni ki wọn ri i daju pe wọn ri awọn to sa lọ mu, kawọn ileewosan naa si ta ọlọpaa lolobo ti wọn ba ri ẹni to gbe ọgbẹ ibọn wa sọsibitu.