Ọlọpaa ti mu Imaamu ijọ Kamọrudeen ati atọkun eegun Eṣuleke to koju ija sira wọn l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Ikọ awọn ọlọpaa ti wọn n ṣewadii wahala to bẹ silẹ laarin awọn ọmọ ijọ Kamọrudeen Central Mosque, Oluọdẹ Aranyin, niluu Oṣogbo, atawọn eleegun lọjọ Aiku, Sannde, to kọja, ti mu eeyan mẹta satimọle bayii.

A gbọ pe awọn ikọ ọga ọlọpaa to n n ṣiṣẹ ọtẹlẹmuye, Inspector General of Police Intelligence Response Team, ni wọn ranṣẹ si Imaamu mọṣalaaṣi naa, Quoseem Yunus, laago mẹwaa alẹ ọjọ Wẹsidee lati beere ọrọ lọwọ rẹ, latigba naa ni wọn si ti ti i mọle.

Oloye Kayọde Eṣuleke, ẹni to ni eegun Eṣubiyi ni wọn ti kọkọ ti mọle lọjọ Tusidee, ko too di pe wọn tun fi pampẹ ọba gbe ọmọkunrin rẹ, Fashọla Eṣuleke, lọjọ Tọsidee.

Idi ti wọn fi mu Imaamu Yunus ko ṣẹyin ẹsun ti awọn eleegun fi kan an pe diẹ lara awọn naa ṣeṣe lasiko wahala to mu ẹmi ẹni kan lọ ọhun.

Aarẹ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ l’Ọṣun, (Traditional Religion Worshippers in Osun State), Dokita Oluṣeyi Atanda, sọ pe aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, lawọn ọlọpaa lọọ gbe Fashọla ninu ile rẹ.

Atanda fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati yanju ọrọ naa nitubi-inubi laarin awọn abala mejeeji ti ọrọ kan.

Bakan naa ni agbẹjọro fun awọn ijọ Kamọrudeen Society, Hashim Abioye, sọ pe lẹyin tawọn eleegun sọ pe awọn ọmọ ijọ naa ṣe awọn leṣe lasiko wahala naa lawọn ọlọpaa ranṣẹ si Imaamu Yunus laago mẹwaa alẹ Ọjọruu, Wẹsidee.

 

 

Leave a Reply