Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori obinrin to ra ọmọ ọsẹ kan tọwọ tẹ ni Sango-Ọta

Gbenga Amos, Ogun

 Obinrin agbalagba ẹni ọdun mẹtalelaaadọta kan, Chinyere Nwozu, to ji ọmọọlọmọ gbe, ikoko ọmọ ọsẹ kan pere, lati Agege, nipinlẹ Eko, wa si Sango-Ọta, ti ko sakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, wọn si ti sọ ọ sahaamọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ.

Owurọ ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje yii, lọwọ ba Chinyere, nigba tawọn eeyan ṣadeede ri ọmọ kekere lọwọ ẹ, tọmọ naa n sunkun asun-i-dakẹ, ti ‘iya ọmọ’ ọdaran yii ko si le fọmọ ọhun lọyan bo ṣe yẹ ki abiyamọ gidi ṣe, wọn ni niṣe lo kan n dawọ bo ọmọ lẹnu, to n pariwo ‘yee ke, yee ke’ lasan.

Eyi lo fu awọn aladuugbo lara, ni wọn ba sun mọ ọn, wọn bi i leere boya oun lo ni ọmọ naa, o loun ni iya ẹ, oun ṣẹṣẹ bi i ni, ni wọn ba ni ko fun un lọyan niṣeju awọn tori igbe ọmọ yii pọ ju, ibẹ lakara ti tu sepo.

Kia ni wọn gba afurasi ọdaran yii mu, wọn si pe ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Sango-Ọta lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti. Oju-ẹsẹ ni DPO teṣan naa, SP Dahiru Saleh, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ, ti wọn si mu un.

Lagọọ ọlọpaa, obinrin naa jẹwọ pe ni tododo, oun kọ loun bi ọmọ toun gbe dani ọhun, oun ra a ni, o lọwọ obinrin kan, Abilekọ Ngozi Akaeme, loun ti ra a l’Agege, ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira, ati pe oun o mọ boya obinrin naa lo bimọ ọhun tabi oun kọ.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tẹkọ leti lọ s’Agege, nibi ti Chinyere sọ pe Ngozi Akaeme n gbe, wọn si ri i mu. Wọn lobinrin naa jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun ati Chinyere ti mọra tipẹ, awọn si ti n ṣe kara-kata ikoko tipẹ, o ni ki i ṣe pe awọn ji ọmọ gbe o, iya to bi ọmọ naa gba lati ta a fawọn ni, oun loun ra a, toun si ṣe ara-tunta ẹ fun Chinyere.
Awọn ọlọpaa ni ko mu awọn lọ sọdọ iya to ta ọmọ naa fun wọn, ṣugbọn niṣe lo ta ku, ko mu wọn lọ, gbogbo arọwa ati isapa awọn ọlọpaa lati jẹ ki wọn ri abiyamọ ti wọn lo ta ọmọ bibi inu ẹ lo ja si pabo.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti ni kawọn mejeeji tọwọ ba yii ṣi maa gbatẹgun lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ, ki wọn le ran wọn lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn. O ni ibi ti iwadii naa ba yọri si lo maa pinnu igbesẹ to kan, lẹyin naa ni wọn yoo foju wọn bale-ẹjọ, gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe sọ.

Leave a Reply