Wọn ti dajọ iku fun ọga ileewe to pa akẹkọọ rẹ

Faith Adebọla

Ṣe ẹ ranti akẹkọọ-binrin ọmọọdun marun-un nni, Hanifa Abubakar, tawọn ọdaju ẹda kan ji gbe lọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun to kọja, lasiko to n ti ileewe Islamiyya rẹ bọ, niluu Kano, nipinlẹ Kano, ti wọn si pa a nifọnna-ifọnṣu lẹyin naa. Ile-ẹjọ ti fidi rẹ mulẹ pe oludasilẹ ileewe Nobel Kids College, Ọgbẹni Hashimu lsyaku, ẹni ọdun mejidinlogoji, ati Abdumalik Tanko, ni wọn huwa odoro naa, wọn si ti dajọ iku fun wọn, wọn ni iru wọn ko tun yẹ lẹni to gbọdọ wa laaye lawujọ eeyan.

Adajọ Usman Na’Abba, tile-ẹjọ giga ipinlẹ Kano, lo gbe idajọ rẹ kalẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjo kejidinlọgbọn, oṣu Keje yii, lẹyin to ti gbọ atotonu agbefọba ati awijare awọn olujẹjọ naa, lati bii oṣu marun-un sẹyin ti igbẹjọ ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ile-ẹjọ ni ẹri to wa niwaju oun, ati ọrọ tawọn ẹlẹrii sọ, ti fidi tẹ mulẹ pe Abdumalik to jẹ olukọ ati oludasilẹ ileewe Sheik Dahiru Bauchi Islamic Foundation, ti ọmọde naa n lọ, lo ji i gbe loju ọna, to si gbe e lọ si Dakata, nijọba ibilẹ Nasarawa, ipinlẹ Kano. Wọn beere pe kawọn obi ọmọ naa lọọ wa miliọnu mẹfa Naira wa kawọn too tu ọmọ ọhun silẹ, ẹnu eyi si lawọn obi naa wa tawọn apaayan yii fi pa a, majele ni wọn lo fun un, ti wọn si wa ilẹ kuṣẹkuṣẹ nileewe Northwest Preparatory School, to wa lagbegbe Kwanar Yan Ghana, nijọba ibilẹ Nasarawa kan naa, ibẹ ni wọn sin oku ọmọọlọmọ si.

Lati le fidi ododo mulẹ, amofin agba fun ipinlẹ Kano, Musa Abdullahi Lawan, to ṣaaju ikọ olupẹjọ, mu ẹlẹrii mẹjọ wa lati fidi ọrọ mulẹ, wọn si ko awọn ẹsibiiti mẹrinla bii awọn fọto oloogbe naa, hijaabu to wọ lasiko ti wọn ji i gbe, ami idanimọ ileewe rẹ atawọn nnkan bẹẹ, silẹ lati kin atotonu wọn lẹyin.

Lara ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi naa, ti wọn si jẹbi rẹ, ni pe wọn paayan, wọn gbiyanju lati paayan, fifi ẹri pamọ ati igbimọ-pọ lati huwa ibi.

Adajọ ni ẹri fihan pe ni tododo, Hashimu ati Abdulmalik jẹbi ẹsun maraarun ti wọn ka si wọn lẹsẹ, o ni ki wọn lọọ ṣẹwọn ọdun kan fun ọkọọkan awọn ẹsun mẹrin, ṣugbọn ni ti ẹsun iṣikapaniyan, o ni ki wọn yẹgi fun wọn ni.

Bakan naa ni ile-ẹjọ da obinrin kan ti wọn loun naa lọwọ ninu iku Hanifa, lẹbi. Ni tiẹ, wọn loun ko jẹbi iṣikapaniyan, ṣugbọn o jẹbi meji ninu awọn ẹsun naa. Amọ nitori o n tọmọ lọwọ, adajọ ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun meji pere, ọdun kan fun ẹsun kọọkan, ati pe yoo ṣẹwọn naa papọ ni.

Leave a Reply