Ọrọ Musulumi meji to fẹẹ dupo aarẹ ati igbakeji ko ba ilana Ọlọrun mu – Dogara

Monisọla Saka

Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin ilẹ wa nigba kan, Yakubu Dogara, ti sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pe bi ajọ ẹgbẹ awọn Onigbagbọ (CAN), ṣe lodi si ki wọn fa aarẹ ati igbakeji to jẹ ẹlẹsin kan naa silẹ ba ilana Ọlọrun mu.

Dogara to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinnu awọn ọmọlẹyin Kirisitẹni naa ni ipinnu awọn to nifẹẹ idajọ ododo.

Olori awọn aṣoju-ṣofin tẹlẹ ọhun sọrọ yii nibi ipade kan ti wọn ṣe nitori gbogbo laasigbo to n ṣẹlẹ lorilẹ-ede yii niluu Abuja, eyi ti wọn fi ṣami ayẹyẹ ọdun kejila apejọpọ awọn ajọ CAN.

O ni, “Mo fẹẹ sọ ọ gbangba gbangba pe, ipinnu awọn CAN lori ẹlẹsin kan naa ti wọn fa kalẹ fawọn ipo to lagbara ju nilẹ yii niru akoko yii ti ilu ko fara rọ ki i ṣe ero CAN tabi Babachir nikan, pupọ eeyan lo ti sọ ọ.

“Mo nigbagbọ pe kikọ ti wọn kọ ki Musulumi meji dupo aarẹ ati igbakeji yii naa ni ohun t’Ọlọrun n fẹ, nitori Ọlọrun to nifẹẹ idajọ ododo la n sin. Oun naa l’Ọba to maa n ṣe eyi to tọ, oun si ni oluda aye, irẹpọ wa lo si n fẹ, toun ti iyapa wa.

“Igbesẹ ati ipinnu CAN yii ni ti gbogbo wa naa, iyẹn awa agba oloṣelu Kirisitẹni, ta a nifẹẹ iṣedeede, idajọ ododo, ta a si n ṣiṣẹ tọ eyi fun idagbasoke orilẹ-ede wa.

“Niwọnba igba to ba ti jẹ pe ipo to tọ la n ja fun, gbogbo ipo to ku ko ba ilana Ọlọrun mu. Ko si ani-ani nibẹ, bakan meji naa si ni, ninu keeyan duro lori idajọ ododo, tabi keeyan maa ṣiṣẹ ta ko iṣọkan orilẹ-ede wa yii”.

Aarẹ ajọ CAN to fẹẹ gbe ijọba silẹ bayii, Samson Ayọkunle, naa fi iye meji han lori awọn INEC pe wọn le ma ṣe eto idibo ọdun to n bọ pẹlu ibẹru Ọlọrun.

O ni, “Mi o lero pe INEC ṣetan lati ṣe eto idibo to yanrannti. Nigba ti mo ko kuro nile ti mo n gbe tẹlẹ lọ sibomi-in, loootọ ninu ilu kan naa ni, ṣugbọn mo ri i daju pe mo tọ awọn ajọ eleto idibo lọ latọdun to lọ ọhun, ṣugbọn titi di akoko yii, ajọ yii ko ti i ba mi ṣe atunṣe si ibudo idibo mi.

“Mo tun pada lọ ninu oṣu Keji, ọdun yii, wọn ni wọn o ti i fontẹ lu u ni olu ileeṣẹ wọn to wa l’Abuja. Ṣe ọrun l’Abuja wa ni.

“Pupọ awọn ọmọ Naijiria ti n wo o pe ọgbọn lawọn INEC n da lati ma ṣe fun awọn ọmọ orilẹ-ede yii laaye lati ṣe ojuṣe wọn lasiko ibo. Ko waa yẹ ki INEC jẹ iṣoro laarin awa ati eto idibo to mọyan lori lọdun 2023”.

Leave a Reply