Lẹyin ọsẹ meji tawọn eleyii tẹwọn de ni wọn tun lọọ jale l’Ẹgbẹda

Monisọla Saka, Eko

Lẹyin ti wọn ja mọto meji gba loju ọna Ẹgbẹda, nipinlẹ Eko lọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọkunrin meji kan.

Ọwọ palaba wọn ṣegi lẹyin ti wọn ji ọkọ Toyota Corolla ti ọdun 2000, to ni nọmba LND-664-GF gbe.

Lọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2022 ta a wa yii ni wọn da Abiọdun Nurudeen, ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36) ati Anthony Richard, toun jẹ ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) silẹ lọgba ẹwọn to wa n’Ikoyi, ko too tun waa di pe wọn ko si panpẹ awọn agbofinro.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ṣalaye pe awọn araalu lo ta awọn lolobo tọwọ fi tẹ wọn.

O ni lagbegbe Lekki ni wọn ti ja mọto naa gba.

Awọn agbofinro waa rọ ẹni to ni ọkọ naa lati yọju, ko si mu ẹri to daju lọwọ nigba to ba n bọ.

Wọn fi kun un pe awọn yoo foju awọn adigunjale naa bale-ẹjọ ni kete tawọn ba ti pari iwadii.

Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Abiọdun Alabi, waa fi awọn araalu lọkan balẹ pe awọn eeyan oun yoo tubọ maa sa gbogbo ipa wọn lati daabo bo awọn eeyan orilẹ-ede yii.

Leave a Reply