Lati asiko yii lọ, ọlọpaa ijọba apapọ ko gbọdọ mu ẹni ti wọn n wa nipinlẹ kan lai gbaṣẹ lọwọ gomina ibẹ-Awọn gomina Guusu

 Faith Adebọla, Eko

  Awọn gomina mẹtadinlogun lati agbegbe Guusu ilẹ wa ti ṣepade nla kan niluu Eko, wọn si ti dori ipinnu pe ipo aarẹ Naijiria gbọdọ maa yipo laarin agbegbe  Ariwa ati Guusu ni, ati pe ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023 yii, ko gbọdọ si aarẹ lati ilẹ Hausa, ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo nikan lo le fa aarẹ jade.

Ọjọ Aje, Mọnde yii, ni wọn ṣepade ọhun ni gbọngan apero to wa nile ijọba ipinlẹ Eko, eyi to wa ni Alausa, Ikẹja, nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti alaga awọn gomina naa, Ọgbẹni Oluwarotimi Akeredolu ti i ṣe gomina ipinlẹ Ondo sọ pe lara awọn ipinnu wọn ni pe lati asiko yii lọ, ko gbọdọ si ọlọpaa tabi agbofinro eyikeyii lati ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to gbọdọ waa fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni ni awọn ipinlẹ Guusu lai jẹ pe gomina ipinlẹ bẹẹ ba mọ si i ṣaaju, to si yọnda fun wọn.

Bẹẹ ni wọn ṣepinnu pe iṣẹ ti gbọdọ pari ofin to ta ko fifi maaluu jẹko ni gbogbo awọn ipinlẹ mẹtadinlogun ilẹ Guusu ṣaaju tabi ni ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ki gomina si buwọ lu u.

Leave a Reply