Awọn adigunjale pa ọlọpaa mẹrin, wọn tun fọ banki n’Ikire ati Apomu

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, ko sẹni to ti i le sọ pato iye eeyan to ku ninu iṣẹlẹ ole jija to waye ni nilee ifowopamọ First bank to wa n’Ikire, ati Access bank to wa l’Apomu, nipinlẹ Ọṣun. Eyi to ṣẹlẹ nirọlẹ  Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu keji yii.

Ṣugbọn ohun ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun,CSP  Yẹmisi Ọpalọla, fidi ẹ mulẹ fun akọroyin wa ni pe o kere tan, ọlọpaa mẹrin lo ba iṣẹlẹ yii rin, nigba tawọn adigunjale naa ya bo teṣan ọlọpaa Ikire, ti wọn si pa ọlọpaa mẹrin ki wọn too morile awọn ileefowopamọ mejeeji yii.

Lẹyin ti wọn kuro ni teṣan ni wọn gba banki lọ ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ, niṣe ni wọn pin ara wọn ti wọn si fọ awọn ilẹkun abawọle awọn banki ọhun. Asiko kan naa ti wọn ṣọṣẹ n’Ikire ni wọn tun n digunjale l’Apomu, ti wọn kowo nla lọ.

Yatọ si oku ọkunrin kan to wa nilẹẹlẹ yii , a gbọ pe awọn onibaara mi-in tun ku iku ojiji lawọn banki yii, latari ibọn tawọn ẹruuku naa n yin leralera.

Aibalẹ ọkan ṣi han loju awọn olugbe agbegbe mejeeji ti idigunjale yii ti waye, jinni-jinni rẹ si wa lara awọn eeyan bi kaluku ṣe royin ohun toju wọn ri.

Leave a Reply