Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nitori bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ati Aye ṣe di ẹrujẹẹjẹ sawọn eeyan lọrun kaakiri ipinlẹ Ogun, awọn ọlọpaa bẹrẹ si i dọdẹ wọn, ni bayii, wọn ti ri awọn kan mu, wọn si ni iṣẹ naa ṣi n tẹsiwaju, ọmọkọmọ tọwọ ba tẹ pe o n ṣẹgbẹ okunkun yoo fimu danrin.
Ọjọruu, ọjọ kejidinlogun, oṣu kọkanla yii, ni DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun, gbe awọn orukọ kan jade pẹlu fọto awọn gende tọwọ ba pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn.
Awọn tọwọ ba naa ni: Tọheeb Ẹrinoṣo, Olufunṣọ Moyọ, Sanya Ayinde, Ramọn Oyetọla, Akinyẹmi Ọlamide, Mọnsuru Akindele, Adeọba Saheed ati Babalọla Rasaq.
Ibọn ibilẹ mẹta lawọn agbofinro gba lọwọ wọn, bẹẹ ni wọn si ti jẹwọ pe ọmọ Aye atọmọ Ẹyẹ lawọn loootọ.
Ṣe laipẹ yii ni ija agba buruku waye laarin awọn ẹgbẹ okunkun mejeeji yii, oju mọmọ ni wọn ti n da wahala silẹ n’Itori ati Abẹokuta. Gẹgẹ bawọn ọlọpaa si ti wi, ko din leeyan mẹrin to ku iku ojiji latọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii.
Nigba ti wahala wọn pọ ni CP Lanre Bankọle paṣẹ pe kawọn ọlọpaa tu jade, ki wọn wa awọn ọmọ to n yọ aye lẹnu naa jade nibi yoowu ti wọn ba fori pamọ si, eyi lo fa a ti ikọ to n ri si ẹgbẹ okunkun ninu iṣẹ ọlọpaa ṣe fi kun iṣẹ wọn nipa didọdẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kaakiri ipinlẹ Ogun.
Amọran ti waa lọ sọdọ awọn obi, pe ki wọn kilọ fawọn ọmọ wọn nipa ẹgbẹ buburu ṣiṣe.
Awọn ọlọpaa sọ pe ọmọkọmọ tọwọ ba tẹ pe o n ṣẹgbẹ okunkun ko ni i lọ lai jiya.