Ọlọpaa ko lẹtọọ lati beere iwe-ọkọ lọwọ dẹrẹba, ẹ tẹle wọn lọ si teṣan ti wọn ba fẹẹ mu yin – Odumosu

Faith Adebọla, Eko

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, ti bẹnu atẹ lu ẹsun tawọn araalu fi  kan awọn ọmọọṣẹ rẹ nipinlẹ Eko, o ni oun yoo wadii awọn ẹsun naa, tori awọn ko fun ọlọpaa eyikeyii laṣẹ lati da onimọto duro maa beere iwe ọkọ, o ni iwa to lodi sofin ni.

Bakan naa lo sọ pe ẹsun gbigba riba ti wọn fi kan awọn ọlọpaa Eko ki i ṣe ẹbi awọn ọlọpaa naa nikan, bi ọlọpaa ṣe jẹbi iwa ibajẹ naa lawọn araalu to n fun wọn naa lufin ọba.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ori redio kan to waye lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee yii, nileeṣẹ STAR FM, l’Ekoo, ni ọga ọlọpaa naa ti ṣalaye ọhun.

Ọgbẹni Miṣah to loun n gbe ni Magodo Estate, lo pe lori aago lati beere lọwọ kọmiṣanna boya o lẹtọọ kawọn ọlọpaa maa da ọkọ duro nirona, ki wọn lawọn n beere awọn iwe ọkọ. Odumosu si fesi pe awọn o fun ọlọpaa laṣẹ iru iwa bẹẹ, o ni ohun tawọn ọlọpaa le ṣe lawọn agbegbe pato kan ti wọn yan fun wọn ni lati da ọkọ duro, ki wọn si yẹ inu ọkọ naa wo boya o lẹbọ lẹru, eyi ti wọn n pe ni “Stop and Search”, o ni ki i ṣe gbogbo ọkọ ni wọn gbọdọ da duro tori eyi pẹlu, kidaa awọn ọkọ ti wọn ba fura si ni.

“Ta a ba fẹẹ yẹ awọn iwe-ọkọ, iyẹn patikula (particulars) ọkọ, wo, o maa n ni akoko pato ti a maa n ṣe’yẹn, a si ti maa kede ṣaaju fawọn onimọto ki wọn le ko patikula mọto wọn dani, tori ki i ṣe gbogbo igba lonimọto le maa ko awọn iwe ọkọ rẹ kiri, paapaa to ba jẹ orijina, tori ewu awọn ole ati ajinigbe. O le jẹ ọjọ mẹrin si marun-un pere la maa ṣe e lati mọ boya awọn ọkọ to n rinna niwee to yẹ, ti iwe naa si muna doko. Yatọ siru asiko akanṣe to jẹ gbogbogboo bẹẹ, ko si ọlọpaa to gbọdọ maa beere iwe ọkọ nirona lai nidii,” gẹgẹ bo ṣe wi.

“Ni ti gbigba riba, ṣe ẹ mọ pe eeyan o le fi ọwọ kan patẹwọ, o gbọdọ pe meji. Ti ko ba si ẹni to maa fun wọn ni riba, ko le si ẹni to maa gba a. Tori naa, mo rọ ẹyin onimọto ati araalu lati dẹkun fifi riba lọ awọn agbofinro, o lodi sofin lati ṣe bẹẹ.

Lọpọ igba, awọn eeyan funra wọn ni wọn maa n fi riba lọ ọlọpaa, paapaa ti wọn ba lawọn maa mu wọn de teṣan. Mo n sọ fun yin, ẹ tẹle wọn lọ si teṣan ni, ẹ ma fun wọn lowo, gbogbo awọn DPO teṣan la ti fun ni itọni lori ọrọ yii, ko si DPO to maa ti yin mọle lainidii. Ṣugbọn nitori awọn eeyan n kanju, tabi wọn ro pe wahala ọlọpaa ti pọ ju, wọn fẹẹ tete lọ, wọn maa maa fi owo kọbẹ lọ wọn, lati fi wọn lọrun silẹ, ko daa bẹẹ rara.

Gbogbo igba ta a ba gbọ nipa awọn ọlọpaa to lọwọ siwa ibajẹ l’Ekoo la maa n gbe igbesẹ lori wọn, lati yọ kan-n-da inu irẹsi kuro. A fẹ kẹyin araalu naa ran wa lọwọ ni.”

Leave a Reply