Ọlọpaa meji ku, awọn mẹjọ tun fara pa ninu ijamba ọkọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Awọn ọlọpaa meji ni wọn ku, ti awọn mẹjọ si tun fara pa yannayanna ninu ijamba ọkọ to waye l’Akurẹ laaarọ ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Ijamba ọkọ yii lo ṣẹlẹ niwaju ile-itura kan ti wọn n pe ni Joe Jane, loju ọna Ọba-Ile, niluu Akurẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọkọ tawọn ọlọpaa bii mejila ọhun wa ninu rẹ lo takiti takiti leralera lẹyin ti ọkan ninu awọn taya rẹ fọ lori ere loju ọna alabala mẹfa naa. Ere asapajude ti wọn n sa ni wọn lo fa iṣẹlẹ naa.

Loju ẹsẹ ni meji ti ku ninu wọn, ti awọn mẹjọ mi-in si tun farapa.

Wọn ti ko oku awọn to ku sinu ijamba ọkọ naa lọ si mọsuari ile-iwosan ijọba to wa l’Akurẹ, ile-iwosan awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Alagbaka ni wọn ko awọn to fara pa lọ fun itọju.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Nitori to ni oun yoo fopin si eto aabo ni Borno ati Yobe, PDP Ekiti sọrọ si Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ẹgbẹ PDPipinlẹ Ekiti ti yẹgẹ ẹnu si gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: