Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ibẹrubojo ti ba awọn eeyan ipinlẹ Ekiti bayii lori iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan to fẹẹ maa di nnkan ojoojumọ bayiii pẹlu bi awọn kan ṣe tun pa Pasitọ Kayọde Ogunlẹyẹ sinu igbo.
Oloogbe naa ni ALAROYE gbọ pe wọn deede pa sinu igbo kan to wa lọna Aramọkọ-Ekiti si Ijero-Ekiti, lasiko to lọ soko lati ka ọgẹdẹ.
Pasitọ Ogunlẹyẹ to jẹ alufaa nileejọsin All Christian Fellowship la gbọ pe awọn eeyan deede ba ninu igbo naa ti ẹjẹ bo o, bẹẹ ni awọn apa to wa lara ẹ fi han pe wọn yinbọn pa a ni.
Eyi lo jẹ kawọn eeyan bẹrẹ si i pariwo pe ọrọ eto aabo ipinlẹ Ekiti ti mẹhẹ nitori iṣẹlẹ naa waye lẹyin ọjọ kan pere tawọn adigunjale kọlu banki kan niluu Iyin-Ekiti, bẹẹ ileeṣẹ ọlọpaa gan-an ti kọkọ kede pe awọn ọdaran kan ti wọ ipinlẹ naa.
Pasitọ tawọn agbebọn pa yii tun jẹ oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti kọlọjọ too de, awọn Fulani darandaran lọpọ awọn to wa lagbegbe naa si gba pe wọn ṣeku pa a.
Nigba to n ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn to ṣiṣẹ laabi ọhun nitori awọn agbofinro gba pe wọn pa a ni.