Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori Tunji tawọn kan pa sinu ile ẹ n’Ibokun

Florence Babaṣọla

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Ọpalọla, sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ iṣekupani to ṣẹlẹ niluu Ibokun, nijọba ibilẹ Obokun, nipinlẹ Ọṣun lọjọ Aje, Mọnde, ọse yii.

Gẹgẹ bi Ọpalọla ṣe wi, alẹ ọjọ Aje ni ọkunrin kan, John Ọlaoye, lọọ fi to awọn agbofinro to wa ni ‘A Division’, niluu Ileṣa, leti pe awọn kan pa Tunji Ajakaye sinu ile ẹ niluu Ibokun.

John ṣalaye fawọn ọlọpaa pe ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun yii, lawọn kan deede wọnu ile Tunji, ti wọn si yinbọn fun un laya.

Lẹyin ti wọn yinbọn fun un tan ni wọn gbe mọto Toyota Camry rẹ sa lọ. Awọn araadugbo sare gbe e lọ sileewosan Wesley Guild Hospital, n’Ileṣa, ṣugbọn ko pẹ to debẹ lo gbẹmi-in mi.

Ọpalọla fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pẹlu ileri pe laipẹ lọwọ awọn ọlọpaa yoo ba gbogbo awọn amookunṣika naa.

 

Leave a Reply