Ọlọpaa ti mu Otubọ, ọkunrin ẹgbẹ ẹ lo ki mọlẹ laarin oru to fẹẹ maa ṣe ‘kinni’ fun l’Oṣodi

Faith Adebọla, Eko

Ọkunrin kan, Jane Otubọ, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, lagbegbe Yaba, o ti n ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ, wọn lọkunrin ẹgbẹ ẹ lo fẹẹ fipa ba lo pọ tọwọ awọn agbofinro fi tẹ ẹ.

Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe sọ, wọn ni ori ikanni atẹ ayelujara kan lafurasi ọdaran ti wọn lo n gbe Ojule kẹta, Opopona Ẹniọla, ni Mafoluku, l’Oṣodi, ti pade Ọgbẹni Francis Azeez, agbegbe Gwagwalada, niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, lawọn mejeeji jọ n ṣọrẹ, wọn jọ n ṣaati (chat).

Ibi ti wọn ti n sọrọ loorekoore yii ni wọn ni Otubọ ti ṣeleri fun Francis pe oun aa da a lokoowo, oun aa si ran an lọwọ, o ni ko waa ba oun l’Ekoo kawọn jọ foju rinju, kawọn le jọ sọ bi bisinẹẹsi naa aa ṣe bẹrẹ.

Francis ṣalaye fawọn ọlọpaa pe ohun ti ko jẹ koun fura si ọkunrin ti wọn lọmọ bibi ipinlẹ Enugu ni yii ni pe funra ẹ lo fowo ti oun maa fi wọkọ ofurufu wa s’Ekoo ṣọwọ sinu akaunti oun, lai mọ oun ri, loun naa ba gbera, o mori le Eko lọsẹ to kọja, ọdọ ọrẹ rẹ yii lo de si.

Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, sọ pe ninu alaye ti Francis ṣe ni teṣan ọlọpaa Makinde, l’Oṣodi, nigba to waa fẹjọ sun, o ni ọrọ bisinẹẹsi lawọn kọkọ n sọ, afi bo ṣe di oru Ọjọruu, Wẹsidee, ti olugbalejo oun bẹrẹ si i fọwọ pa oun lara, to n fọwọ pa oun labẹ nigba toun sun lọ, titaji toun taji, o ni ihooho goloto lọkunrin naa wa, o si ti bu ṣokoto oun so, o loun fẹ kawọn jọ laṣepọ, loun ba yari mọ ọn lọwọ.

Francis ṣalaye siwaju si i pe ijakadi gidi lawọn ba ara awọn ja, tori ọkunrin naa ni afi dandan ni koun ṣe ‘kinni’ foun lai ki i ṣe obinrin, ariwo kitakita tawọn n ṣe lo ji awọn araale silẹ, eyi lo mu ki ọkunrin kan ti wọn n pe ni aafaa tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago  loru naa, n ni wọn ba waa fi pampẹ ọba gbe afurasi ọdaran ọhun.

Wọn ni lanlọọdu ile naa tun ṣalaye fawọn ọlọpaa pe ọkunrin yii ko ṣẹṣẹ maa huwa palapala ọhun, lanlọọdu ni ọpọ igba loun ti pari aawọ latari bawọn eeyan ṣe n n fẹjọ tẹnanti yii sun pe o n fi ilọkulọ lọ awọn.

Bo tilẹ jẹ pe okoowo awọn nnkan jijẹ ni afurasi ọdaran naa loun n ṣe, awọn aladuugbo naa ni irin ẹsẹ rẹ ko mọ, wọn lọganjọ oru lo maa n wọle lọpọ igba, ẹnu si ti n kun un laduugbo pe afaimọ ni ko ma jẹ oniṣẹẹbi ẹda kan ni, wọn ni boya tori ẹ lọkunrin naa ṣe n pe ara ẹ ni Jane.

Ṣa, ọrọ rẹ ti detiigbọ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, o si ti ni ki wọn fa a le ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun iwadii gidi, lẹyin eyi lo maa lọọ ṣalaye ara ẹ ni kootu laipẹ

Leave a Reply