Ọlọpaa ti tiṣa lu ọmọ rẹ l’Ekiti n beere fun miliọnu mẹẹẹdogun naira lọwọ ijọba

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọlọpaa kan, Elijah Agenoisa, ti n beere miliọnu mẹẹẹdogun naira lọwọ ijọba ipinlẹ Ekiti bayii gẹgẹ bii owo ‘gba ma binu’, nitori ọmọ rẹ, Gift  Agenoisa, ti tiṣa na lẹgba nileewe girama Mary Immaculate, l’Ado-Ekiti.

Ile-ẹjọ ni Elijah gba lọ, iyẹn lẹyin to ni oun ti kọwe siyawo gomina ipinlẹ Ekiti, pe ki wọn da si ọrọ ọmọ oun naa, ṣugbọn ti wọn ko dahun. Kootu lo n ran sijọba bayii lati ba a gba owo naa jade pẹlu bo ṣe pe ijọba ipinlẹ Ekiti lẹjọ.

Ṣe ni ogunjọ, oṣu karun-un, ni Gift, ọmọ Sajẹnti Elijah, gẹ irun buruku lọ sileewe, awọn alaṣẹ ileewe naa si da a dọbalẹ, wọn fun un lẹgba mẹwaa nidii, wọn si tun fun un niwee gbele-ẹ fun asiko diẹ, ko le jẹ ẹkọ fọmọ naa pe ofin wa nileewe yii to yẹ kọmọ gidi tẹlẹ.

Ohun to ṣẹlẹ yii bi Sajẹnti Elijah ninu, ẹsẹkẹsẹ lo si ko ọlọpaa mẹrin lẹyin lati ba awọn olukọ to lu ọmọ rẹ naa ja.

Ninu iwe ipẹjọ to pe lorukọ iyawo rẹ, Ọdunayọ Agenoisa, ni wọn ti ṣalaye pe titẹ ẹtọ ọmọ naa loju mọlẹ lawọn ara ileewe naa ṣe.

Agenoisa sọ pe bi wọn ṣe lu ọmọ oun to wa ni kilaasi akọkọ (JSS 1), lodi sofin, nitori wọn gba ẹjẹ lara rẹ, lilu naa si di aarẹ si i lara to jẹ oun tun lọọ n nawo itọju ni.

Yatọ si eyi, olupẹjọ yii sọ pe bi wọn ṣe ni kọmọ oun lọọ jokoo nile lodi sofin pẹlu, o ni ki wọn da a pada, kijọba si san miliọnu mẹẹẹdogun owo gba-ma-binu foun.

Awọn ti Sajẹnti Elijah Agenoisa pe lẹjọ ni ọga agba patapata nileewe naa, Arabinrin Oluwasanmi F. M, Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ekiti, Dokita Olabimpe Aderiye, ajọ olukọ nipinlẹ Ekiti ati ijọba ipinlẹ Ekiti.

Igbẹjọ di ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021.

Leave a Reply