Olori aṣọfin ipinlẹ Ogun dero ile-ẹjọ, EFCC lo gbe e lọ

Gbenga Amos, Ogun

Igbẹjọ ti bẹrẹ lakọtun lori ẹsun ole jija ati ikowojẹ ti wọn fi kan olori awọn aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Taiwo Ọlakunle Oluọmọ, ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Eko nigbẹjọ naa ti waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an ta a wa yii.

Yatọ si Oluọmọ, awọn afurasi ọdaran meji mi-in ti wọn jọ fẹsun kan naa kan, ti wọn si jọ kawọ pọnyin rojọ ni Ọgbẹni Samuel Ọladayọ to jẹ alamoojuto eto iṣunna owo ileegbimọ aṣofin Ogun ati Akọwe ileegbimọ aṣofin naa, Ọgbẹni Taiwo Adeyẹmọ.

Adajọ Daniel Emeka Osiagor lo wa lori aga idajọ.

Nnkan bii aago mẹwaa aabọ owurọ ni wọn fi ọkọ piikọọpu funfun kan to jẹ ti EFCC ko awọn olujẹjọ naa wọnu ọgba kootu ọhun, ko si ju bii ọgbọn iṣẹju lẹyin naa ni gbogbo wọn fara han niwaju adajọ.

EFCC, to n gbogun ti iwa jibiti lilu, kikowojẹ lẹnu iṣẹ ọba ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu (Economic and Financial Crimes Commission) lo wọ awọn afurasi naa rele-ẹjọ lorukọ ijọba apapọ.

Ẹsun mọkanla ọtọọtọ to da lori ṣiṣe ayederu iwe owo, pipaarọ akọsilẹ ijọba, irọ pipa, ole jija, pipa owo ilu ni pompo, ati nina owo ilu ti iye rẹ n lọ bii biliọnu meji aabọ Naira (N2.5b) fun anfaani ara-ẹni ni wọn ka si wọn lọrun.

Ọkan lara awọn ẹsun naa, gẹgẹ bi wọn ṣe ka a si wọn leti sọ pe:

“Iwọ, Oluọmọ Ọlakunle Taiwo, Ọladayọ Samuel, Adedeji Taiwo ati Adeyanju Nimọta to ti sa lọ bayii, gbimọ-pọ laarin ara yin lọdun 2019 ni Abẹokuta, lati na owo ti aropọ rẹ jẹ biliọnu meji, miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta din mẹẹẹdọgbọn Naira (N2.450billion) lara owo ilu to wa nikaawọ yin fun ilo tara yin, ẹ si tipa bayii rufin jiji owo ko ninu asunwọn ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, eyi to ta ko isọri kẹjọ ati isọri kẹẹẹdogun iwe ofin tijọba fi ka ikowojẹ leewọ lọdun 2011, eyi ti ijiya to gbopọn wa fun”.

Bẹẹ ni wọn ka gbogbo awọn ẹsun mẹwaa yooku jade lọkọọkan.

Ṣugbọn awọn olujẹjọ mẹtẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun wọnyi.

Agbẹjọro to ṣoju fun wọn pe akiyesi adajọ si ẹbẹ awọn onibaara rẹ pe kile-ẹjọ faaye beeli silẹ fun wọn, ki wọn le maa tile waa jẹjọ, adajọ si beere lọwọ olupẹjọ boya o ta ko ẹbẹ naa tabi o fara mọ ọn, o loun fara mọ ọn, eyi lo mu ki adajọ yọnda pe ki wọn gba beeli wọn.

Amọ o, adajọ ni Oluọmọ gbọdọ ni owo ti iye rẹ to ọọdunrun miliọnu Naira ninu akaunti rẹ, o si gbọdọ wa oniduuro meji ti ọkọọkan wọn ni iye owo kan naa ninu akaunti wọn, ati pe oniduuro naa gbọdọ jẹ ọga agba to ti de ipele kẹrindinlogun lẹnu iṣẹ ọba, wọn si gbọdọ ni dukia to jọju ni sakaani ile-ẹjọ naa.

Ni ti awọn olujẹjọ meji yooku, o ni beeli wọn gbọdọ to ọgọrun-un miliọnu Naira, pẹlu ẹlẹrii meji-meji ti wọn ni iye owo kan naa lọwọ, ti wọn si jẹ ọga to wa nipele kẹrinla lẹnu iṣẹ ọba. Wọn tun gbọdọ ni dukia ti ko jinna si sakaani kootu ọhun, ki wọn too le lọ sile wọn.

Bakan naa ni Adajọ Osiagor tun paṣẹ pe ki wọn gbawe irinna, iyẹn pasipọọtu gbogbo wọn lọwọ wọn, ki wọn ko o fun akọwe kootu ọhun titi ti igbẹjọ yoo fi pari. O ni kawọn ti wọn fẹẹ ṣoniduuro mu iwe-ẹri ‘mo ti sanwo-ori mi’ jade, fun ọdun mẹta sẹyin, o kere tan, ki wọn si ṣebura nile-ẹjọ.

Tẹ ẹ o ba gbagbe, owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an yii, lawọn ẹṣọ EFCC rẹbuu olori awọn aṣofin ipinlẹ Ogun naa, Oluọmọ, ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed, n’Ikẹja, bo ṣe n bọ lati Abuja, ti wọn si lọọ fọrọ wa a lẹnu wo lọfiisi wọn to wa ni Ikoyi, l’Erekuṣu Eko. Ẹyin eyi ni wọn wọn ọkunrin naa sọkọ pada siluu Abuja, lolu-ileeṣẹ ajọ EFCC, nibi ti wọn ti n ba iwadii niṣo, ki wọn too tu u silẹ laaarọ ọjọ Satide.

Ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn tun ni ko pade awọn ni kootu giga ipinlẹ Ogun kan, l’Abẹokuta, lati kootu naa ni wọn si ti fi pampẹ ofin gbe oun atawọn olujẹjọ yooku, ti wọn si gba iyọnda lati lọọ bẹrẹ ẹjọ naa lakọtun niluu Eko.

Leave a Reply