Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Araba Awo ti ilu Oṣogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, ti sọ pe Olori Ọọni Ogunwusi tẹlẹ, Naomi Ṣilẹkunọla, le fẹ ọkọ miiran ni bayii to ti pingaari pẹlu Ọọni, ṣugbọn o ni awọn igbesẹ to gbọdọ gbe ko too le ṣe bẹẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu Alaroye ni Baba Ẹlẹbuibọn ti ṣalaye pe aini amumọra ati igbọra-ẹni-ye lo fa a ti igbeyawo Arole Oduduwa fi da bii ẹni pe o n fori ṣanpọn.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ko si nnkan kan to n ṣẹlẹ si kabiesi, ṣe ẹ mọ pe ọrọ ọkọ ati iyawo, oju Ọlọrun lo le to o. Ninu igbeyawo, ọkọ atiyawo nilo ibagbepọ pẹlu amumọra lọna kin in ni ati ọna keji. Ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe egun, ki i ṣe epe, wọn ko gbọ ara wọn ye ni.
“Nilẹ Yoruba, gbogbo iyawo teeyan ba fẹ ni a ki i fẹ ki wọn kọ ọkọ, ki i ṣe Olori nikan, ṣugbọn to ba waa de ikorita ti apa ọkọ tabi iyawo ko ka a mọ, teeyan ri i pe o yẹ keeyan yago funra eeyan, ko si eewọ nibẹ.
“Nigba ti igbeyawo ba fẹẹ fa ipalara fun ọkọ tabi iyawo, eeyan le yẹra. Ṣugbọn gbogbo igbeyawo nilo amumọra ko baa le t’ọjọ”
Nipa pe ṣe Olori Ṣilẹkunọla le lọ fẹ ọkọ miiran lẹyin to ti bimọ kan fun Ọọni Ifẹ, Oloye Ẹlẹbuibọn ṣalaye pe “Iyẹn waa wa lọwọ rẹ o, yala o fẹẹ fẹ ọkọ miiran tabi o fẹẹ duro bẹẹ.
“Ṣugbọn o, ko sẹni to le deede fẹ iyawo ọba, wọn ni lati kọkọ mu ọwọ ọba kuro lara rẹ ko too fẹ ẹlomi-in, o ni iwẹ ti yoo wẹ, o ni etutu ti yoo ṣe, ti ko ba ṣe bẹẹ, o lewu. Ọba ki i ṣe ẹni teeyan le deede daya de iyawo rẹ, eeyan o gbọdọ bayawo ọba sun nigba to wa labẹ orule ọba, ka too wa sọ ti ẹni to ba gba a sọdọ.
“Ẹni to ba maa fẹ ẹ gbọdọ ni suuru, tori orukọ ọba ni gbogbo nnkan to wa lara rẹ bayii, oro ọba lo wa lara rẹ, o ni lati pada si ẹsẹ aarọ ko too le fẹ ẹlomi-in, yoo ri bo ṣe ri tẹlẹ, igba naa lo le fẹ ẹlomi-in.”