Stephen Ajagbe, Ilọrin
Oku olori oṣiṣẹ gomina Kwara, Oloogbe Aminu Adisa Logun, ti wọ kaa ilẹ nirọlẹ oni nile rẹ to wa lọna Ijumu, niluu Ilọrin.
Imaamu to dari eto isinku naa, Dokita Abubakar Imam Aliagan, ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii alaaanu ati ẹni to nifẹẹ si irẹpọ laarin ẹbi.
“Latigba ta a ti mọ Alhaji Aminu Adisa Logun, eeyan jẹjẹ la mọ ọn si. Mo ranti igba to wa si mọṣalaṣi ẹbi wa, o funra rẹ ṣe atunṣe kan lara ileejọsin naa.”
Aliagan gbadura pe ki Ọlọrun gba oloogbe naa gẹgẹ bii ọkan lara awọn iranṣẹ rẹ tootọ, ko si fi ọrun kẹ ẹ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana ni Logun dagbere faye lẹyin to ko arun Koronafairọọsi.
Lara awọn to wa nibi eto isinku naa ni igbakeji gomina, Kayọde Alabi, akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Saba Jubril, oludamọran pataki si gomina lori ọrọ oṣelu, Saadudeen Salaudeen, awọn akẹgbẹ rẹ to mojuto akanṣe iṣẹ, Yinka Aluko, ti ẹsin Musulumi, Zubair Dan Maigoro atawọn mi-in.