Olukọ meji, akẹkọọ mẹjọ, lawọn agbebọn tun ji gbe nileewe kan ni Kaduna

Faith Adebọla

Ibẹrubojo tun ti gbode kan niluu Zaria, pẹlu bawọn janduku agbebọn kan ṣe ya bo ileewe gbogboniṣe aladaani Nuhu Bamalli Polytechnic, wọn yinbọn pa ọmọleewe kan, wọn ṣe awọn mẹwaa leṣe yannayanna, wọn si ji olukọ meji ati akẹkọọ mejidinlogun gbe sa lọ.

Iṣẹlẹ yii, gẹgẹ bi Kọmiṣanna feto aabo abẹle nipinlẹ Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin, waye loru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Aruwan ni niṣe lawọn agbebọn naa kọkọ ya bo ile tawọn olukọ naa n gbe ninu ọgba ileewe ọhun, ọganjọ oru tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa, ti kaluku ti sun fọnfọn, ni wọn wa, wọn ṣina ibọn bolẹ, ibẹ si lọta ibọn ti ba meji lara awọn akẹkọọ ti ojora ti mu, bi wọn ṣe n sa kijokijo laajin oru naa.

O ni orukọ awọn akẹkọọ meji ti wọn yinbọn lu ni Ahmad Muhammad ati Haruna Isyaku Duniya.

Lẹyin naa lawọn agbebọn ọhun ko awọn akẹkọọ mẹjọ tọwọ wọn ba ati olukọ meji sori awọn akada ti wọn gbe wa, wọn si ko gbogbo wọn wọgbo lo.

Lẹyin tawọn eeyankeeyan naa lọ tan lawọn alaaanu to wa nitosi too le gbe awọn to fara pa atawọn meji tibọn ba lọ sọsibitu kan to wa nitosi, ṣugbọn wọn ni bi wọn ṣe n lọ lọna ni ọkan ninu awọn akẹkọọ naa, Ahmad Muhammad, doloogbe.

O lawọn agbofinro ti de ibi iṣẹlẹ naa, wọn si ti bẹrẹ iwadii ati itọpinpin nipa awọn to ṣọṣẹ yii.

A gbọ pe ọrọ naa ti detiigbọ Gomina Nasir El-Rufai tipinlẹ Kaduna, o si ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn obi ati mọlẹbi awọn akẹkọọ tọmọ wọn ku, atawọn to ṣeṣe.

Eyi ni igba keji tawọn agbebọn n ṣakọlu sileewe yii laarin ọdun kan aabọ sira wọn.

Yatọ si ileewe poli yii, bakan naa lawọn agbebọn ṣakọlu si Greenfield University ati ileewe Federal College of Forestry Mechanisation lẹnu aipẹ yii, ti wọn si ji ọgọọrọ awọn akẹkọọ gbe, bo tilẹ jẹ pe wọn pada tu wọn silẹ lẹyin ti wọn ti gba ọpọ miliọnu owo naira ati ọkada tuntun ti wọn beere fun, ti wọn si ti yinbọn pa diẹ lara awọn akẹkọọ naa nigba tawọn obi wọn ko tete ri owo ti wọn beere fun san.

Leave a Reply