Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede ipinnu rẹ la ti maa fiya jẹ olukọ tọwọ ba tẹ pe o n lo akẹkọọ rẹ ni nilokulo lasiko ti wọn ba wa nileewe.
Oludamọran fun gomina lori akanṣe iṣẹ, Dokita Doyin Ọdẹbọwale, to sọrọ yii lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. O ni ọpọlọpọ awọn olukọ ipinlẹ naa ni ẹsun wọn ti wa niwaju ijọba lori awọn iṣẹ ti ko tọ ti wọn n fun awọn akẹkọọ wọn ṣe nileewe.
O ni oriṣiiriṣii iroyin lawọn n gbọ lori bawọn tiṣa kan ṣe n ko awọn akẹkọọ lọ sile tabi oko wọn la ti ba wọn ṣiṣẹ, leyii to lodi sofin ati ilana to rọ mọ eto ẹkọ ipinlẹ Ondo.
O rọ awọn olukọ ti wọn n hu iru iwa yii ki wọn tete jawọ, nitori pe ijọba ti ṣetan ati fiya to tọ jẹ ẹni to ba tun dan iru rẹ wo.
Nigba to n fun oludamọran ọhun lesi, Alaga ẹgbẹ awọn olukọ ileewe alakọọbẹrẹ, Ọgbẹni Victor Akọmọ, ni ko sibi ti wọn ti n fawọn akẹkọọ ṣiṣẹ ile mọ lasiko ta a wa yii.
O ni kijọba lọọ fọkan balẹ, nitori pe ahesọ lasan ni iroyin ọhun jẹ.