Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọba Ezekiel Abidoye Oyeniyi, Arowooṣilejoye, ti i ṣe Olumoro ti Moro, nijọba ibilẹ Ariwa Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun ti waja.
Ọdun mọkandinlogoji ni baba naa lo lori itẹ awọn baba nla rẹ ko too rewalẹ aṣa.
Onimọ iṣegun oyinbo ni ẹka iṣẹ-abẹ (ENT Surgeon) ni Ọba Oyeniyi, o si ti ṣiṣẹ lorileede United Kingdom, Naijiria, Saudi Arabia ati bẹẹ bẹẹ lọ ko too di pe o gun ori-itẹ awọn baba nla rẹ.
O ti lo ọpọ ọdun lori itẹ ko too di pe Ọọni Ifẹ ana, Ọba Okunade Ṣijuwade, gbe ade fun un lọdun 1995.
Pupọ awọn ọmọ ilu Moro ni wọn n royin kabiesi naa gẹgẹ bii ọba to fẹran ẹkọ iwe pupọ, wọn ni ko si ipejọpọ to wa ti ko ni i maa pariwo pe ki awọn obi fun awọn ọmọ wọn lẹkọọ to ye kooro.