Ọmọ Yahoo fi mọto tẹ eeyan mẹta pa lasiko tawọn EFCC n le wọn ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Eeyan mẹta ni wọn ku l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji yii, l’Opopona Olóoru, Kàǹǹbí, nijọba ibilẹ Móòrò, nipinlẹ Kwara, lasiko ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, n le awọn afurasi ọmọ Yahoo lọ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meji ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni awọn ọmọ Yahoo ti wọn wa ọkọ ayọkẹlẹ Range Rover kan ati awọn oṣiṣẹ EFCC, kan to wa ọkọ bọọsi alawọ funfun n le ara wọn bọ lati ọna Fasiti KWASU, niluu Màlété. Ṣugbọn nigba to ku diẹ ki wọn de ilu Kàńńbí, ni awọn EFCC bẹrẹ si i yinbọn si wọn, wọn yinbọn si taya mọto wọn. Taya ọhun to fọ lo mu ki awọn ọmọ Yahoo yii maa le dari ọkọ mọ, lasiko naa ni wọn kọ lu ọkada kan ti Fulani mẹta wa lori ẹ, ọkunrin meji, obinrin kan, ti awọn mẹtẹẹta si ku loju-ẹsẹ.

Lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn to ni ka forukọ bo ohun laṣiiri ṣalaye fun ALAROYE pe akẹkọọ Fasiti ipinlẹ Kwara (KWASU), ni afurasi awọn ọmọ Yahoo naa, bi ibọn awọn EFCC ṣe ba taya ọkọ wọn lo lọọ kọ lu awọn Fulani mẹta lori ọkada, tawọn mẹtẹẹta si ku. Lẹyin naa ni ọkọ yii mori wọ igbo lọ. O ni igi ti ọkọ naa kọ lu lo fi duro, tawọn ọmọ Yahoo naa si raaye fẹṣẹ fẹ ẹ.

O tẹsiwaju pe bi wọn ṣe n sa lọ ni awọn EFCC n pariwo, ‘ole, ole’. Wọn pada ri awọn ọmọ Yahoo naa mu, ṣugbọn niṣe ni awọn mọlẹbi Fulani ti wọn pa bẹrẹ si i sa awọn ọmọ Yahoo naa ladaa yanna yanna, tawọn EFCC si sa lọ ni tiwọn. Ọpẹlọpẹ awọn Yoruba to wa nibi iṣẹlẹ yii ni wọn gba awọn ọmọ Yahoo naa silẹ, wọn sọ fun awọn Fulani pe wọn ki i ṣe ole, akẹkọọ KWASU ni wọn.

Owuyẹ yii ni awọn ajọ ẹṣọ alaabo ojupopo ni wọn waa doola ẹmi awọn ọmọ Yahoo ọhun, ti wọn si gbe wọn lọ sileewosan olukọni Fasiti ilu Ilọrin, (UITH), fun itọju to peye. A gbọ pe mọlẹbi awọn Fulani to ku sinu iṣẹlẹ naa ti ko oku wọn lọ lati lọọ sin wọn.

Bakan naa lo ni awọn ọlọpaa ti gbe mọto ati ọkada lọ si Agọ ọlọpaa iluu Kàńńbí.

Alukoro ajọ FRSC nipinlẹ Kwara, Ọlayinka Basambo, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ohun ti wọn sọ fawọn ni pe ijamba ọkọ sẹlẹ, awọn si ti ko awọn to fara pa lọ si ileewosan olukọni Fasiti tiluu Ilọrin (UITH), fun itọju to peye.

 

Leave a Reply