Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn ajinigbe meji, wọn doola ọmọleewe ti wọn ji gbe

Monisọla Saka

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ awọn ole ajọmọgbe meji kan, Bọlajoko Haruna ati Adamaka Chinyere, ti wọn ji akẹkọọ-binrin kan gbe.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ọdun yii, ni Benjamin Hundeyin, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọrọ naa di mimọ.

Alukoro ni akiyesi tawọn araadugbo tọrọ naa ti ṣẹlẹ lagbegbe Ikọtun, nipinlẹ Eko, ṣe ti wọn fi pe awọn agbofinro, ati bawọn ọlọpaa ṣe tete debẹ lo jẹ ki wọn ri awọn afurasi mejeeji, ọkunrin kan ati obinrin ọhun mu, ti wọn si ri ọmọ ti wọn ji gbe sinu mọto gba layọ ati alaafia.

Lori ayelujara lo kọ ọ si pe, “Teṣan ọlọpaa agbegbe Ikọtun, gbọ iroyin awọn eeyan kan ti wọn n rin irin to mu ifura dani ninu adugbo.

Lẹyẹ-o-sọka lawọn ọlọpaa ti debẹ, wọn si ribi doola ọmọbinrin ile ẹkọ sẹkọndiri kan ti wọn ti tan wọnu mọto wọn.

“Wọn ti mu awọn afurasi ọhun, ọkọ Toyota Camry wọn ti wọn pa laro teeyan ko fi ni i ru inu ọkọ lati ita paapaa ti wa lakata awọn ọlọpaa”.

Hundeyin sọrọ siwaju si i pe ni kete ti iwadii ba ti wa sopin ni wọn yoo ko awọn afurasi lọ sile-ẹjọ.

Bakan naa lo sọ pe wọn ti ri awọn obi ọmọ naa, wọn si ti fa a le wọn lọwọ.

O waa rọ awọn araalu lati kọ awọn ọmọ wọn, pe iru ohun yoowu ti wọn ibaa fi tan wọn, ki wọn ma ṣe tẹle ẹnikẹni ti wọn ko ba mọ ri.

Leave a Reply