Oluwoo gba Tinubu nimọran: Ẹ ṣi bọda, ki ẹ si gbẹsẹ  lori fifofin de kiko ounjẹ wọle

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Latari wahala ọwọngogo ounjẹ to n mu awọn eeyan orileede Naijiria fojoojumọ pariwo, Oluwoo ti ilu Iwo nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, ti ke si Aarẹ Bọla Tinubu lati ṣi awọn ẹnu ibode (Borders) orileede yii.

Bakan naa ni ọba alaye ọhun rọ Aarẹ lati gbe ẹsẹ kuro lori ofin tijọba fi de kiko awọn ohun eelo ikọle wọ orileede yii lati oke-okun.

O ni ọna kan ṣoṣo lati ma ṣe faaye gba gudugbẹ ebi ọgaja-fọwọ-mẹkẹ to n fi loke yii lati ja ni ki ounjẹ wọle sorileede yii lọpọ yanturu.

Ninu atẹjade kan ti kabiesi fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, to fi ṣọwọ si ALAROYE lo ti ṣalaye pe igbesẹ naa jẹ eyi tijọba apapọ gbọdọ gbe kiakia, ko si wa bẹẹ fun odidi oṣu mẹfa, lati fi ka awọn ti wọn n ṣe ọgbin ounjẹ lorileede yii, ṣugbọn ti wọn fi n pọn awọn araalu loju lapa ko.

Pẹlu bi Ọba Akanbi ṣe sọ pe ki Aarẹ Tinubu ṣi awọn ẹnu ibode to wọ ilẹ wa, o ni ki wọn fi ti Niger Republic silẹ ni titi pa gbọingbọin.

Oluwoo tẹ siwaju pe inu awọn ọlọgbin ounjẹ kan lorileede yii n dun si ipenija to n daamu awọn araalu bayii, idi niyẹn tijọba fi gbọdọ fofin de kiko ounjẹ lọ s’Oke-Okun lati orileede yii, ki wọn si faaye gba kiko ounjẹ wọle.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Ara n ni awọn araalu pẹlu bi owo ounjẹ ṣe gbẹnu soke bayii, ijọba si gbọdọ gbe igbesẹ kiakia. Gbogbo ẹnuuloro to wọ orileede yii, yatọ si ti Niger, lo gbọdọ di ṣiṣi, lati mu ki owo ounjẹ walẹ.

‘Aarẹ Ahmed Tinubu gbọdọ faaye gba kiko ounjẹ wọ orileede yii lati ilẹ okeere, ki wọn gbẹsẹ kuro lori ofin ti wọn fi de kiko irẹsi wọle, ti wọn ba le ṣe eleyii laarin oṣu mẹfa pere, iyipada nla yoo ṣẹlẹ.

‘Agbẹyin-bẹbọjẹ ni awọn ọlọgbin ounjẹ ti a ni lorileede yii. A gbọdọ ka wọn lọwọ ko nipa siṣeto orogun-owo fun wọn. Wọn ko gbọdọ ko nnkan ti a n ṣe lorileede yii lọ s’Oke-Okun mọ. Kijọba faaye gba awọn ohun eelo ikọle lati wọle, eleyii yoo din owo awọn nnkan ku’

Leave a Reply