Adiẹ ti jẹ’fun ara wọn o: Umar pa Fulani ẹgbẹ ẹ l’Akoko, o lo n gbero lati ji oun gbe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọkunrin ẹni ogun ọdun kan, Umar Ibrahim, lo ti wa nikaawọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, lori ẹsun ṣiṣe iku pa Fulani ẹgbẹ rẹ kan ti wọn p’orukọ rẹ ni ni Muhammadu Adamu, l’Akunnu Akoko.

Ninu alaye ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Peter Ọladipọ, ṣe fawọn oniroyin lasiko to n ṣe afihan afurasi ọdaran ọhun ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lo ti ni abule kan ti wọn n pe ni Abule Fulani, eyi to wa nitosi Akunnu Akoko, ni Umar ati Adamu jọ n gbe.

Ọjọ keji, oṣu Kin-in-ni, ọdun ta a wa yii, ni Umar lọọ ba ọrẹ rẹ, to si bẹ ẹ pe ko jọwọ, waa fi ọkada baba rẹ gbe oun lọ sibi kan ti wọn n pe ni Ogali, nipinlẹ Kogi, ti ọmọkunrin naa si gba si i lẹnu.

O ni bi awọn ṣe n de inu igbo kan ti ko si ẹnikẹni to n bọ niwaju tabi lẹyin ni Umar fa ada yọ, eyi to fi ṣa ọrẹ rẹ to ni ko gbe oun lọ si ipinlẹ Kogi pa.

Nigba tọwọ awọn agbofinro tẹ afuarsi apaayan ọhun, ti wọn si beere lọwọ rẹ ẹsẹ ti ọrẹ rẹ ṣẹ ẹ to fi ran an ṣọrun ọsan gangan, Umar ni loootọ loun mọ-ọn-mọ pa a lẹyin ti aṣiri tu si oun lọwọ pe Adamu ati ẹnikan to n jẹ Basiru ti ṣeto laarin ara wọn lati ji oun gbe, ki wọn si pa oun.

Kọmiṣanna ọhun ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ Basiru ti wọn darukọ, ti Umar funra rẹ ko si ni i pẹẹ f’oju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ.

 

 

Leave a Reply