Ijọba Kwara pe ipade apero lati gbogun ti lilo egboogi oloro

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulraman Abdulrasaq, lo ṣide ipade pataki kan, nibi ti wọn ti n ṣe apero lati gbogun ti lilo egboogi oloro lorile-ede Naijiria, paapaa ju lọ, nipinlẹ Kwara.

Ipade ọhun bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, nibi ti gomina atawọn alaṣẹ ijọba nipinlẹ naa ti jiroro lori ọna abayọ tuntun lati fopin si awọn to n lo egboogi oloro nipinlẹ Kwara ati Naijiria lapapọ.

Nibi ipade pataki ọhun ni Abdulrasaq, ti ni gbogbo ọgbọn ati ọna tawọn mọ ni iṣejọba awọn n san lati gbe oniruruu eto kalẹ lati ṣe idanilẹkọ fawọn ọdọ lati maa tẹle ilana awọn ẹni iṣaaju, ki wọn si jinna si lilo oogun oloro ati awọn ohun miiran to fara pẹ ẹ nipinlẹ naa.

Gomina ni awọn gbe eto naa kalẹ lati wa ọna abayọ si iṣoro lilo oogun oloro. O ni idi ti iṣejọba oun fi yan Aileru Ọlamilekan Mukail, gẹgẹ bii oluranlọwọ pataki lori egboogi oloro ati idena rẹ ni lati ri i daju pe asilo oogun ati egboogi oloro di afi ṣẹyin ti eegun n fi aṣọ nipinlẹ naa.

Ninu ọrọ ti ẹ, Arabinrin Rinsọla, ni lilo egboogi oloro ti di tọrọ fọnkale lorile-ede yii, to si jẹ pe gbogbo ọmọ Naijiria ni wọn nilo lati fọwọsowọpọ lati gbogun ti lilo ati gbigbe egboogi oloro, paapaa ju lọ laarin awọn ọdọ orile-ede yii.

O tẹsiwaju pe ọpọ awọn ọdọ to ni ọgbọn ati oye ni wọn maa n sọ pe igbo lo n ran awọn lọwọ lati ni ọgbọn inu ati oye ikun. O ni ida ọgọrin awọn to ni arun ọpọlọ lo jẹ pe nipaṣẹ lilo egboogi oloro ni.

O lu Gomina Abdulrasaq lọgọ ẹnu lori igbiyanju rẹ lati gbogun ti lilo egboogi oloro nipinlẹ naa.

Lara awọn alejo pataki to wa nibi ipade ọhun ni alaga igbimọ fun awọn ọdọ ati ere idaraya nileegbimọ aṣofin, Họnarebu Rukayat Shittu, Oluranlọwọ pataki si Aarẹ Tinubu, fun ọrọ jijẹ ọmọ ilu ati adari (Citizenship and Leadership), Arabinrin Rinsọla Abiọla, Kọmiṣanna fun idagbasoke awọn ọdọ, Họnarebu Nafisat Buge, Adari ajọ NDLEA, ẹka tipinlẹ Kwara, Mohammed Bashir Ibrahim, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Leave a Reply