L’Ọṣun, awọn oṣiṣẹ-fẹyinti ranṣẹ si Adeleke

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Awọn oṣiṣẹ ti wọn ti fẹyinti nipinlẹ Ọṣun, laarin ọdun 2011 si 2012 (Forum of 2011/2012 pensioners) ti ke si Gomina Ademọla Adeleke lati mu adehun tijọba ba awọn ṣe lasiko iṣejọba Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ṣẹ.

Nibi ipade oniroyin kan ti wọn ṣe laipẹ yii ni wọn ti ṣalaye pe adehun ti Arẹgbẹṣọla ṣe fun awọn nigba naa ni lati sọ owo-oṣu awọn oṣiṣẹ to kere ju di ẹgbẹrun lọna mejidinlogun Naira, ṣugbọn ti ko mu un ṣẹ.

Gẹgẹ bi alaga wọn, Ileṣanmi Ọmọniyi, sẹ sọ, nigba ti wọn woye pe ẹgbẹrun mẹsan Naira to jẹ owo oṣiṣẹ to kere ju ti Arẹgbẹṣọla n san nigba naa ni wọn yoo tun fi maa fun awọn lowo ifẹyinti, wọn wọ ijọba lọ sile-ẹjọ lọdun 2014.

O ni ile-ẹjọ giga da awọn lare lọdun 2017, wọn si paṣẹ pe kijọba bẹrẹ si i san owo naa, bẹẹ ni ijọba ko gbe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kankan dide laarin aadọrun-un ọjọ, nibaamu pẹlu ofin ilẹ wa, sibẹ, wọn ko tun sanwo ọhun.

Ilesanmi fi kun ọrọ rẹ pe nigba to di ọdun 2021, nijọba ipinlẹ Ọṣun pe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, ti awọn naa si gba agbẹjọro to n ṣoju awọn niluu Akurẹ, titi di ọsẹ to kọja ti kootu fagi le ẹjọ tijọba ipinlẹ Ọṣun pe.

O fẹsun kan agbarijọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti nipinlẹ Ọṣun, iyẹn Nigeria Union of Pensioners, pe gbogbo igbesẹ ti awọn n gbe ni wọn n dabaru titi digba tile-ẹjọ da awọn lare yii.

Bakan naa ni Akọwe wọn, Comreedi Ṣọla Ọlọjẹde, ke si Gomina Ademọla Adeleke

lati san awọn owo wọn pẹlu igbelewọn ẹgbẹrun lọna mejidinlogun Naira gẹgẹ bo ṣe wa ninu idajọ naa.

“Awa o fẹẹ ba ijọba ja, gbogbo ijọba to ba ti wa nipo ni tiwa. A mọ pe idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yẹn aa ti de ọdọ gomina, ki wọn pe ipade, ki wọn si ri i daju pe awọn ṣe amuṣẹ ohun to wa ninu idajọ naa.”

 

Leave a Reply