Awọn ọmọ Yahoo la lọọ ja lole tọwọ fi tẹ wa- Saliu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Adeyẹye Saliu, lọwọ awọn agbofinro ti tẹ lẹyin toun atawọn awọn ọmọ ẹgbẹ adigunjale rẹ lọọ ja awọn eeyan kan lole lagbegbe Ìṣùàdà, nijọba ibilẹ Ọwọ.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe, Saliu atawọn ikọ rẹ mẹta mi-in ni wọn lọọ ja ọmọbinrin kan ti wọn pe ni Miracle, ati ẹnikan ti wọn n pe ni Mustapha lole, lagbegbe Oriya, Ìṣùàdà, nitosi Ọwọ, ni nnkan bii aago mẹsan-an ku iṣẹju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, ti wọn si digun ja wọn lole owo to to bii miliọnu kan aabọ Naira.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Peter Ọladipọ, ni Saliu nikan lọwọ awọn ṣi tẹ ninu awọn ẹgbẹ adigunjale ẹlẹni mẹrin naa, ati pe akitiyan awọn agbofinro ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn ẹgbẹ rẹ to sa lọ mu kiakia.

Nigba ti ALAROYE n fọrọ wa Saliu lẹnu wo lo ti ṣalaye fun akọroyin wa pe awọn ọmọ Yahoo nlo maa n jẹ afojusun awọn lati ja lole, o ni awọn ki i ja awọn mi-in lole ju awọn ọmọ Yahoo lọ.

Ọmọkunrin yii ni awọn mẹrin lawọn jọ n jale loootọ, ṣugbọn oun nikan lọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ lẹyin ti awọn ti kọkọ ṣe aṣeyọri nibi ti awọn ti lọọ digunjale.

Ọmọkunrin to pe ara rẹ ni ọmọ bibi ilu Ọwọ ọhun ni iṣẹ awọn to n lẹ taisi ile loun kọ, bẹẹ ni ohun to sun oun dedii idigunjale ko ye oun rara.

 

Leave a Reply