Awọn ọlọpaa ti mu Sanni, wọn lo mọ nipa akẹkọọ-binrin Fasiti Akungba ti wọn gun pa laipẹ yii

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọlọpaa ti fi pampẹ ofin gbe afurasi ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Olubọdun Sanni, lori bi wọn ṣe pa Adekunle Adebisi Ifẹoluwa to jẹ akẹkọọ-binrin Fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu Akungba Akoko, nipakupa mọ’nu yara rẹ lọjọ keji, oṣu Keji, ọdun 2024 yii.

Ifẹoluwa to wa ni ipele kẹta ni Fasiti Adekunle Ajasin ni wọn ba ninu agbara ẹjẹ ninu yara ile to n gbe lọjọ naa, ti ko si ṣẹni to le sọ bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye gan-an.

Ninu alaye ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Peter Ọladipọ, ṣe fun wa, o ni ohun ti awọn agbofinro kọkọ ṣakiyesi nigba ti wọn ṣe abẹwo sibi iṣẹlẹ naa ni foonu rẹ ti wọn ji lọ.

Foonu yii lo ni awọn tọpa rẹ pẹlu ṣiṣe amulo awọn irinṣẹ igbalode, titi tọwọ fi tẹ Sanni, ẹni to wa ni ipele aṣekagba ni Fasiti Akungba kan naa, to si tun jẹ ọkan ninu awọn alabaagbelepọ Oloogbe ọhun nigba aye rẹ.

O ni Sanni pada jẹwọ lasiko ti awọn agbofinro n fọrọ wa a lẹnu wo pe loootọ loun yọ wọnu yara Ifẹoluwa, nibi ti oun ti gun un lọbẹ laya, ki oun too ji foonu rẹ gbe sa lọ.

O na akọroyin wa lọpọlọpọ wahala ki Sanni too gba lati sọ ohun to mọ lori ẹsun ti wọn fi kan an pẹlu bi ọmọkunrin ta a n sọrọ rẹ yii ṣe yari kanlẹ pe oun ko ni i ba ẹnikẹni sọrọ.

Lẹyin ọpọlọpọ arọwa, o ba wa sọrọ, o si fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ka foonu oloogbe ọhun mọ oun lọwọ, ṣugbọn oun kọ ni oun pa a.

O ni ṣe ni oun ra foonu naa lọwọ ẹnikan ti oun ko mọ rara, bẹẹ loun ko ti i san kọbọ fun ẹni ọhun ki wọn too mu oun.

Kọmiṣanna ni ko ni i pẹ rara ti afuarsi ọhun yoo fi foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Leave a Reply