Damilọla yii laya o, ọlọpaa lo ja lole ni Ṣúpáre Akoko, o tun ji ibọn ẹ lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kayeefi patapata lọrọ ọmọkunrin kan ti wọn p’orukọ rẹ ni Arogubdade Damilọla, jọ loju gbogbo awọn to wa nibi tawọn ọlọpaa ti ṣe afihan oun atawọn afurasi ọdaran kan ni olu ileeṣẹ wọn to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji yii, nigba to n sọrọ lori ọna to fi ja odidi ọlọpaa lole ibọn AK47 kan niluu Ṣúpáre Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko.

Nigba to n sọrọ lori bọwọ ṣe tẹ ogbologboo adigunjale ọhun, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Peter Ọladipọ, ni awọn eeyan kan lo kọkọ ta awọn lolobo pe awọn ri nnkan kan to jọ ibọn lọwọ ọmọkunrin ẹni ogun ọdun ọhun.

O ni ohun tawọn ọlọpaa tesan Ìwárọ̀ Ọka Akoko gbọ ree ti wọn fi kẹṣẹ bọ iwadii ọrọ naa titi tọwọ fi tẹ Damilọla pẹlu ibọn nla ti wọn ka mọ ọn lọwọ.

O ni oun funra rẹ si jẹwọ fawọn agbofinro to fọrọ wa a lẹnu wo pe iṣẹ ole loun n ṣe lagbegbe Akingbade, ati pe ori-oke aja ile ẹnikan loun ti ji ibọn naa gbe ni Ọgangan, nitosi Ṣúpáre.

Ninu ọrọ diẹ ti afurasi ọhun ba wa sọ lasiko ti a n fọrọ wa a lẹnu wo, Damilọla ni iṣẹ ole jija loun n ṣe loootọ, o ni ori-oke aja ile ọlọpaa kan ti oun lọọ fọ loun ti ṣalabaapade ibọn naa, ti oun si ji gbe e.

Afurasi ọdaran yii ni oun ko mọ ariwo ti wọn waa n pa le oun lori, nitori oun ko fi bo rara fun wọn pe ọlọpaa loun ja l’ole ibọn rẹ, ti wọn si ti gba ẹru ofin naa pada lọwọ oun lọjọ gan-an ti oun ji i gbe.

 

Leave a Reply