O ma ṣe o, lẹyin bii oṣu kan aabọ ti wọn rọ ọ loye, alaga ẹgbẹ PDP tẹlẹ l’ Ondo ku lojiji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, (PDP) tẹlẹ nipinlẹ Ondo, Ọnarebu Fatai Adams, ni wọn ti kede iku rẹ lẹyin bii ọjọ mẹtalelogoji ti wọn yẹ aga mọ ọn nidii gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun  yii, ni ọkunrin ọmọ bibi Ìrùn Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun  Akoko, ọhun bẹrẹ si i kigbe ori fifọ ninu ile rẹ to n gbe niluu Akurẹ.

Loju-ẹsẹ ni wọn l’awọn eeyan to wa pẹlu rẹ si ti sare gbe e lọ sile-ewosan kan, nibi to pada ku si lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn gbe e debẹ.

Adams ni wọn yan gẹgẹ bii alaga PDP nipinlẹ Ondo ni kete ti alaga ẹgbẹ ọhun tẹlẹ, Clement Faboyede, pari saa rẹ lọdun diẹ sẹyin.

Ọjọ keji, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024 yii, lawọn oloye ẹgbẹ PDP kan nipinlẹ Ondo, kede pe awọn ti yọ ọ nipo gẹgẹ bii alaga, ti igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ ọhun si fontẹ lu iyọnipo naa lọjọ kẹrin, oṣu yii kan naa.

 

 

Leave a Reply