Ni bayii, lọọya Naijiria le ṣiṣẹ ni UK, gẹgẹ bi ti UK naa ṣe ti le ṣẹ ni Naijiria

Monisọla Saka

Ijọba ilẹ United Kingdom, ti tọwọ bọwe ajọṣepọ pẹlu ilẹ Naijiria, lati le fawọn agbẹjọro lorilẹ-ede mejeeji laaye lati ṣiṣẹ niluu ara wọn.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti ijọba UK fi atẹjade sita ni wọn ti ni iru ajọṣepọ bayii yoo bi oniruuru anfaani lẹka eto okoowo ati idajọ.

Ilẹkun anfaani to ṣi silẹ yii yoo faaye gba awọn ọmọ ilẹ Naijiria ti wọn jẹ amofin lati ṣiṣẹ tabi rojọ fun onibaara wọn nilẹ UK, bẹẹ ni tawọn UK naa yoo lanfaani lati ṣiṣẹ wọn nilẹ Naijiria.

Ninu atẹjade ọhun ni wọn ti tun sọ pe eto yii yoo mu ki ajọṣe nidii iṣẹ tiata ati amuluudun gbooro, bẹẹ ni yoo tun jẹ anfaani fawọn ileeṣẹ eto ẹkọ UK, lati pese ẹkọ to ye kooro nilẹ Naijiria.

“Eto ajọṣepọ The Enhanced Trade and Investment Partnership (ETIP) yii, ni akọkọ iru ẹ ti ilẹ UK yoo ba orilẹ-ede Afrika kankan ṣe, bẹẹ ni pataki nnkan ti wọn fi ṣe e ni lati mu agbega ba ọrọ aje orilẹ-ede mejeeji.

“Orilẹ-ede Naijiria lo ni eto ọrọ aje to duroore ju lọ, to si ni idagbasoke ju lọ nilẹ Afrika. Bẹẹ ni ajọ iṣọkan agbaye, United Nation (UN), ti ni iye eeyan to wa lorilẹ-ede naa yoo fẹrẹ to ilọpo meji, bii miliọnu lọna ọrinlelọọọdunrun (370m) o din diẹ eeyan, nigba ti yoo ba fi di ọdun 2050”.

Akọwe okoowo fun orilẹ-ede UK, Kẹmi Badenoch, ti i ṣe ọmọ ilẹ Naijiria ati UK, to ti wa ni orilẹ-ede Naijiria fun eto ayẹwo ọlọjọ mẹta naa fi kun un pe, ọna lati mu ki ajọṣepọ to dan mọran ati eto ọrọ aje to gbamuṣe wa laarin orilẹ-ede mejeeji lo bi adehun tuntun ọhun.

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, kan naa ni Badenoch ati minisita fọrọ okoowo nilẹ Naijiria, Doris Nkiruka Uzoka-Anite, ti jọ tọwọ bọwe adehun naa niluu Abuja.

Lasiko to wa lorilẹ-ede yii, Badenoch yoo tun lo anfaani yii lati yọju si Charterhouse School, ti i ṣe ileewe aladaani ilẹ UK, akọkọ nilẹ Afrika. Bakan naa ni yoo tun ṣabẹwo si olori banki apapọ ilẹ wa, ati minisita fọrọ owo nina, lati le fopin si awọn idena to n ba idokoowo laarin ilẹ Naijiria ati UK.

 

Leave a Reply