O tan! Adajọ ti ju ayederu dokita to n lu araalu ni jibiti sẹwọn n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ giga kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ ju ayederu Dokita oniṣegun oyinbo kan, Chidiebere Cyril Ndigwe, sahaamọ ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun jibiti lilu ti wọn fi kan an, ati  pe ki i ṣe ojulowo dokita to n pera ẹ.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ wa, ‘Economic And Financial Crimes Commision’ (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, lo wọ Ndigwe lọ siwaju Ile-ẹjọ fẹsun olonka meji ọtọọtọ, lilu awọn araalu ni jibiti pẹlu ileri pe oun yoo ba wọn wa iṣẹ ati pipe ara rẹ ni ojulowo dokita oniṣegun oyinbo nileewosan olukọni Fasiti Ilọrin (University of Ilọrin Teaching Hospital), leyii ti wọn lo ta ko iwe ofin ilẹ wa.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni EFCC foju Ndigwe bale-ẹjọ lori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an ọhun.

Ninu ọrọ olupẹjọ to n ṣoju ajọ EFCC, Mustapha Kaigama, lo ti ṣalaye ni kootu pe ṣe ni afurasi yii parọ fun awọn araalu pe ojulowo dokita oniṣegun oyinbo loun nileewosan olukọni Fasiti Ilọrin, to si n lu wọn ni jibiti.

Mustapha, ni ṣe ni afurasi yii n lo oju opo ibanidọrẹẹ rẹ (Facebook), lati fi lu jibiti ọhun, yoo sọ pe aaye si silẹ nileewosan olukọni fasiti ọhun, ti yoo si ni ki awọn to ba ni iwe ẹri to ti kawe gboye waa ra fọọmu ni ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (400,000), ti yoo si sọ pe ki awọn to ba ni iwe-ẹri diploma san ẹgbẹrun lọna igba (200,000)gẹgẹ bii owo fọọmu ti oun yoo si fun wọn niṣẹ. O tẹsiwaju pe afurasi naa ti lu awọn eeyan ni jibiti owo to to miliọnu mejidinlogun Naira (18M), ko too di pe ọwọ tẹ ẹ bayii.

O ni laarin ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, si ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, ni o lu Arabinrin kan, Rukayat Jọkẹ Yusuf, ni jibiti miliọnu mẹfa Naira labẹ didibọn pe oun yoo ba a wa iṣẹ pẹlu iwe-ẹri fasiti ati ti diploma, eyi ti ifiyajẹni rẹ si wa ninu iwe ofin ilẹ wa ọdun 2006.

Onidaajọ Adenikẹ Akinpẹlu, ni afurasi naa ko ni ẹri lati fi gbe ọrọ rẹ lẹṣẹ, fun idi, eyi oun ko le gba beeli rẹ. O paṣe pe ko maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun ti wọn fi kan.

Leave a Reply