Wọn gba ayederu oṣiṣẹ LASTAMA yii mu l’Ekoo, owo nla to gba lọwọ onimọto lo ko ba a

Adewale Adeoye

Yoruba bọ, wọn ni, ‘ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun’, bẹẹ gan-an lo ri fun ayederu oṣiṣẹ LASTAMA kan, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, ẹni ọdun mẹrindinlọgọta ti awọn agbofinro ipinlẹ Eko fọwọ ofin mu laipẹ yii pe o n pe ara re ni oṣiṣẹ ajọ to n dari igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, ‘Lagos State Traffic Management Agency’ (LASTMA).

Ọjọ ti pẹ diẹ ti ọdaran ọhun pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan ti n lọ kaakiri aarin ilu Eko, ti wọn aa si maa pe ara wọn ni oṣiṣẹ ajọ LASTMA ti wọn ko jẹ. Wọn maa gbowo lọwọ awọn onimọto gbogbo ti wọn ba mu fun ẹsun kan tabi omiiran, lẹyin naa ni wọn aa sa lọ, ti wọn aa si da awọn ẹni ti wọn gbowo lọwọ wọn si ironu nla.

ALAROYE gbọ pe ẹgbẹrun lọna ogoje Naira ni Ọgbẹni Fẹmi ṣẹṣẹ gba lọwọ araalu kan pe oun maa ba a gba mọto rẹ kan ti wọn fofin de jade, ṣugbọn ti ko mu ileri rẹ ṣẹ rara. Owo ọhun lo pada waa ko  ba a to fi di pe wọn fọwọ ofin mu laipẹ yii.

Ọga agba ajọ ọhun, Ọgbẹni Ọlakekan Bakare-Oki, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, rọ awọn araalu, paapaa ju lọ, awọn onimọto, pe ki wọn ṣọra gidi fawọn ayederu oṣiṣẹ LASTAMA, ti wọn n lọ kaakiri, ti wọn si n gbowo lọwọ awọn araalu lọna aitọ bayii. O ni oṣiṣẹ LASTMA kankan ko lẹtọọ rara labẹ ofin ilu Eko lati gbowo lọwọ awọn to ba ṣẹ sofin irinna ilu Eko, pe banki tijọba ipinlẹ naa fọwọ si nikan lawọn alaṣẹ ni ki awọn araalu maa sanwo si nigba gbogbo ti wọn ba fẹẹ sanwo itanran ohun ti wọn ṣe.

Oki ni awọn ti da awọn ẹka ajọ amunifọba to n gbogun ti titẹ ofin loju mọlẹ niluu Eko, ‘Lagos State Task-force’ sita lati maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn ọbayejẹ ti wọn fẹẹ ba orukọ daadaa ajọ naa jẹ laarin ilu.

Oki ni, ‘Iroyin buruku ta a maa n gba lati ọdọ awọn araalu tawọn ayederu oṣiṣẹ LASTAMA yii n gbowo lọwọ wọn nigba gbogbo lo ka wa lara, ta a fi dọdẹ wọn, ọwọ tẹ Ọgbẹni Fẹmi to gbowo gọbọi lọwọ dẹrẹba mọto kan pẹlu ileri pe oun maa ba a gba mọto ti ajọ ọhun gba lọwọ rẹ jade, ṣugbọn to gbowo olowo sa lọ. Awọn ọrẹ ọdaran ọhun ti sa lọ bayii, ṣugbọn awọn ọlọpaa ṣeleri fun wa pe awọn maa too fọwọ ofin mu wọn laipẹ yii.

Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Fẹmi ni, ‘Loootọ ni mo gba ẹgbẹrun lọna ogoje Naira lọwọ araalu kan pẹlu ileri pe ma a ba a gba mọto rẹ tawọn oṣiṣẹ ajọ LASTMA gba lọwọ rẹ jade, emi nikan kọ ni mo n ṣiṣẹ laabi ọhun, mo ni awọn ọrẹ ti ki i ṣe ojulowo oṣiṣẹ LASTMA, ojoojumọ la maa n gbowo lọwọ awon araalu ti wọn fẹẹ gba mọto wọn jade lọgba LASTMA, o kere tan, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira ni ẹni kọọkan wa maa n pin lọsọọsẹ.

O loun kabaamọ ipa buruku toun ko ninu iṣẹ laabi ọhun, bakan naa lo ṣeleri pe b’oun ba bọ ninu wahala naa, oun ko ni i dan iru aṣa palapala bẹẹ wo mọ lae.

Leave a Reply