Oluwoo gboṣuba fawọn aṣofin Ogun lori ofin ti wọn ṣe nipa ilana isinku awọn ọba

Ọlawale Ajao, Ibadan

Oluwoo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti fi atilẹyin rẹ han si ipinnu ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lori ilana ti wọn n gba yan ọba ati bi wọn ṣe n ṣeto ikẹyin fun ọba to ba waja ni ipinlẹ naa.

Oluwoo tun gboṣuba fun awọn to dabaa ọhun, to fi mọ Awujalẹ ti Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna, Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, Akarigbo tilu Rẹmọ, Ọba Adeniyi Sonariwo, Olu ti Yewa, Ọba Kẹhinde Olugbenle, fun igbesẹ akin ti wọn gbe lori ọrọ yii.

Ọba Akanbi, ninu atẹjade ti akọwe iroyin rẹ, Alli Ibraheem, buwọ lu sọ pe igbẹsẹ naa jẹ ọna kan gboogi lati fi oju awọn ọdọ si aṣa ati iṣe Yoruba.

O ni abadofin yii yoo gba awọn ọba kalẹ lọwọ ijẹgaba awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun.

Lara awọn ayipada ti abadofin naa dabaa rẹ ni pe ki wọn maa sin awọn ọba ni ilana ẹsin wọn. Oluwoo ni awọn oniṣẹṣe to n fẹhonu han ta ko aba yii kan fẹẹ fa ọwọ aago igbesẹ naa sẹyin ni.

O waa rọ awọn ileegbimọ aṣofin yooku lati wo awokọṣe igbesẹ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun yii.

Leave a Reply