Omi ni Fridauz lọọ pọn lodo to fi gan mọ’na n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọmọdebinrin ẹni ọdun mejila kan, Fridauz, ti dero ọrun bayii pẹlu bo ṣe pade iku ojiji lagbegbe Ogidi, Ọlọjẹ, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (South), omi lo lọọ pọn lodo to fi gan mọ ina.

ALAROYE gbọ ni aṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni ọmọdebinrin naa lọọ pọnmi nibi kanga-dẹrọ ti ko jinna si ile wọn, bo ṣe pọn omi tan to n ru u lọ sile ni waya ina ẹlẹntiriiki kọ ijaabu rẹ, bo ṣe fẹẹ yọ ijaabu, waya ina ẹlẹntiriiki lo gba mu, lo ba gan mọ ina. Awọn araadugbo gbinyanju lati doola ẹmi pẹlu bi wọn ṣe gbe e lọ sileewosan kan to wa ni agbegbe naa, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, ọmọ naa pada ku.

Ileewe girama Ọlọjẹ Community, ni wọn sọ pe ọmọ naa n lọ, to si wa ni ipele keji ninu ọdun mẹta akọkọ (JSS 2), nileewe naa. Wọn ti sinku ọmọ naa nilana ẹṣin Musulumi.

Leave a Reply