Ọmọ Buhari ni, ‘Ti Naijiria ba ku, ikoriira lo pa a’

Aderounmu Kazeem

Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, oluranlọwọ fun Aarẹ Muhammed Buhari, lo sọrọ kan sinu iwe iroyin laipẹ yii, ohun to si sọ ni pe, ti Naijiria, ba fi le ku, ikorira ti awọn eeyan ni si i ati sira wọn gan an lo pa a.

Wahala nla to n ṣelẹ lọwọ lori iwọde tawọn ̀ọdọ n ṣe lati fi tako iwa ipaniyan atawọn iwa janduku mi-in ti awọn ẹṣọ agbofinro SARS, n hu lo bi ọrọ ọhun.

Ohun ti Fẹmi Adeṣina si sọ ni pe bawo ni iwọde wọọrọ ṣe le dohun ti ẹmi n bọ, ti awọn ọdọ n jo ile, ti wọn n ba dukia jẹ, tawọn mi-in ti wọn ti ni ikusinu sira wọn tẹlẹ n lo anfaani ọhun lati fi kọlu ara wọn, ti wọn si sọ gbogbo ibilkibi ni Naijriia doju ogun.

O ni, ni kete ti asopọ ti waye laarin awọn eeyan Guusu ati Ariwa, eyi to bi orukọ orilẹ-ede yii lọdun 1914, eyi tawọn eeyan kan n ri i bayii gẹgẹ bii aṣiṣe. O ni latigba ti asopọ yii ti waye ni wahala ti bẹrẹ tawọn eeyan paapaa ko gba ara wọn gbọ, ti awọn ti wọn jẹ olori naa n lepa ara wọn kiri, ti wọn n fọbẹ ẹyin jẹ ara wọn niṣu.

Adeṣina, fi kun un pe niwọn igba ti awọn ti wọn jẹ olori ẹsin ti n ṣe waasu ni mọṣalaṣi ati ni ṣọọṣi tako ijọba to wa lori ipo, tawọn oloṣelu paapaa ti wọn ko rọwọ mu ninu ibo kan tabi omi-in ti n lo anfaani kekere ti wọn ba ni lati kona mọ wahala lọjọ ti anfaani ẹ ba ti yọ, ni wọn ti n wa opin si ohun to n jẹ Naijiria lọnakọna.

“Ti orilẹ-ede yii ba ku, yala nisiniyi tabi lọjọ iwaju, dajudaju ikorirra tawọn eeyan ni si i ni ati eyi ti wọn ni sira wọn paapaa. Abi bawo ni eeyan ṣe le ni ikorira nla fun orilẹ-ede ẹ atawọn alaṣẹ, ki iru ilu bẹẹ ni alaafia ati ilọsiwaju gidi, ati pe onkọwe kan sọ pe, ‘Lọjọ ti eeyan ko ba ri ẹni ti yoo korira mọ, niṣe niru wọn maa n korira ara wọn’.

“Wẹrẹ bayii lọrọ iwọde tako SARS bẹrẹ pẹlu erongba gidi, ki wọn too sọ ọ di rogbodiyan, tawọn eeyan ti wọn ko rọwọ mu ninu ibo oṣelu lọdun 2015 ati 2019 si bẹrẹ si lo anfaani wahala tọrọ ọhun da silẹ lati da ilu ru, ti wọn fe ki Naijiria pin yelẹyelẹ.”

Fẹmi Adeṣina, fi kun un pe Aarẹ Muhammed Buhari ti ṣeleri wi pe atunṣe gidi yoo ba ọrọ awọn ọlọpaa, bẹẹ nijọba paapaa yoo ṣiṣẹ lori ohun gbogbo tawọn ọdọ n beere fun, ki alaafia le jọba.”

 

Leave a Reply