Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kayeefi lo ṣi n jẹ fawọn eeyan Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, pẹlu bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ṣe ya bo ileewe girama Muslim to wa niluu ọhun laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ti wọn si tu awọn akẹkọọ ka nibi ti wọn ti n ṣe idanwo ijọba to n lọ lọwọ.
ALAROYE gbọ pe lara awọn akẹkọọ ileewe ọhun ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn waa ṣe akọlu si olukọ atawọn ẹgbẹ wọn ki wọn le dawọ idanwo ti wọn n ṣe naa duro.
Awọn soja to wa lagbegbe Ọrẹ ni wọn pada waa tu awọn janduku akẹkọọ ọhun ka, ti wọn ko fi ri ẹnikẹni ṣe leṣe, ti wọn si tun ri ọkan ninu awọn tọọgi ọhun mu lọ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, adele olukọ agba ileewe girama ọhun, Abilekọ Ẹniọla Moradekẹ, rọ ijọba ipinlẹ Ondo lati ṣeto awọn ẹsọ alaabo ti yoo maa ṣọ wọn laarin asiko ti wọn ba wa nileewe.
O ni eyi nikan lo le fawọn akẹkọọ ati olukọ lọkan balẹ lati gbaju mọ isẹ wọn.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lawọn akẹkọọ kilaasi kejì agba (SS2) kaakiri ipinlẹ Ondo bẹrẹ idanwo tijọba n ṣe fun wọn ki wọn too kọja si ipele aṣekagba (SS3).
Idi tawọn akẹkọọ kan nileewe Muslim ko ṣe fẹẹ kopa ninu idanwo gbogbogboo naa ṣi n ya awọn eeyan lẹnu.