Ọmọ ọdun mẹẹẹdogun gun iyawo ẹgbọn ẹ to loyun oṣu mẹjọ pa

Ohun to kọ lu ọmọkunrin kan tọjọ ori ẹ ko ju mẹẹẹdogun lọ to fi yọ ọbẹ ti iyawo ẹgbọn rẹ to loyun oṣu mẹjọ, to si gun un pa lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu kẹfa, nipinlẹ Kano, ko ti i ye ẹnikẹni titi dasiko yii. Iyanu gbaa ni.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kano, Abdullahi Haruna, lo fi atẹjade to kede iṣẹlẹ yii sita. Alaye ti wọn ṣe ninu ẹ ni pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ naa lawọn gba ipe kan, pe ọmọ ọdun mẹẹẹdogun gun alaboyun pa ni Maidille Quarters, ni Kano.

Niṣe ni wọn ni ọmọkunrin to gun alaboyun oṣu mẹjọ naa ṣadeede wọle ẹgbọn ẹ, to n sọ pe iyawo rẹ ṣaa loun fẹẹ ri. Ẹru ba iyawo naa ti wọn pe orukọ ẹ ni Habiba Isah, o si mu foonu lati pe ọkọ rẹ pe ko maa bọ nile.

Ṣugbọn ọmọ ọdun mẹẹẹdogun naa ko jẹ ko pe ipe ọhun, wọn ni niṣe lo gbe ọmọ-odo nilẹ, to fi gba foonu naa danu lọwọ obinrin oloyun naa, n lo ba fa ọbẹ yọ, o bẹrẹ si i gun un ninu ati kaakiri ara.

Awọn ọlọpaa lo waa gbe oloyun yii lọ sọsibitu ẹkọṣẹ iṣẹgun Amino Kano, awọn dokita gba a wọle, ṣugbọn ko pẹ ti wọn fi sọ fun wọn pe ọmọ inu rẹ ti ku, iya paapaa tẹle e laipẹ rara ni.

Bi ọmọ ọhun ṣe kere to labẹ ofin, iwa ọdaran to hu ti jẹ ki wọn la a mọ ahamọ, nibi to ti n ṣalaye ohun to mu un to fi pa iya atọmọ ti ko ṣẹ ẹ lẹṣẹ kan.

Leave a Reply