Ọmọ ọdun mejila ku sodo to ti lọọ luwẹẹ n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara ti ri oku ọmọdekunrin ti ko ju ọdun mejila lọ ninu odo lọna Ejiba, lagbegbe papa iṣere idaraya niluu Ilọrin.

Atẹjade kan lati ileeṣẹ naa ṣalaye pe adugbo Ọja Iya, niluu Ilọrin, ni ọmọde naa ti wa.

Wọn ni oloogbe naa pẹlu awọn ọrẹ rẹ lo jọ lọọ wẹ lodo Asa, nibi ti omi ti gbe e lọ.

Ileeṣẹ naa ni awọn ti gbe oku ọmọ naa fun baba rẹ, Ọgbẹni Monday Benjamin, loju-ẹsẹ tawọn gbe e jade tan.

Ọga agba ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara,

Falade John Olumuyiwa, ba ẹbi naa kẹdun, o gba awọn obi nimọran lati maa ṣọ irinṣẹ awọn ọmọ wọn lọna ati deena iru iṣẹlẹ buruku bẹẹ lọjọ iwaju.

 

Leave a Reply