Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ba a ṣe n jekuru ko tan lawọn agbenipa sowo n gbọn ọwọ ẹ sawo ni Kwara bayii pẹlu bi ọrọ awọn apaniṣowo ṣe n legba kan si i nipinlẹ Kwara.
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tun tẹ ọkunrin kan, Alade James, lagboole Alawe, niluu Ọffa, lakooko to n bo ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹsan-an, Faith Samuel, to pa mọlẹ pẹlu ẹgbẹrun kan naira ni agbegbe Ikọtun, nijọba ibilẹ Ọffa, ipinlẹ Kwara, to si jẹwọ pe oogun owo loun fẹẹ fi i ṣe.
Ọjọ Aiku, Sunnde, ọṣẹ yii, ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Okasanmi Ajayi, fi iroyin naa lede niluu Ilọrin pe ọwọ ti tẹ arakunrin kan torukọ rẹ n jẹ Alade James, fẹsun pe o ṣeku pa ọmọde ọdun mẹsan-an, Faith Samuel, ti agboole Onireke, niluu Ọffa, to si n bo o mọlẹ pẹlu ẹgbẹrun kan naira.
Nigba ti wọn gbe ọmọ naa jade ninu koto to n bo o mọ ni wọn gbe e lọ si ileewosan, nibi ti wọn ti ṣe ayẹwo fun un. Dokita fidi ẹ mulẹ pe ọmọdebinrin ọhun ti dagbere faye, wọn si ti gbe oku ẹ si yara igbokuu-si nileewosan naa to wa niluu Ọffa. James si jẹwọ pe oogun owo loun fẹẹ fi ọmọdebinrin ọhun ṣe.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo, ti waa paṣẹ pe ki wọn ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa lati mọ igbeṣẹ to kan.