‘Ọmọ ti wọn fi ṣe mi laaanu nigba tọmọ mi ku ni Baba Ijẹṣa fipa ba lo pọ’

Faith Adebọla

Pẹlu bi iwadii tawọn ọlọpaa n ṣe lori ẹsun biba ọmọde ṣeṣekuṣe ati ifipabanilopọ ti wọn fi kan gbajugbaja oṣere onitiata ilẹ wa nni, Ọlanrewaju James Omiyinka tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ṣe n lọ lọwọ, ọpọ aṣiri lo n tu sita nipa bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ati bi ọkunrin naa ṣe ja awọn ololufẹ rẹ kulẹ.

Oṣere-binrin alawada kan, Damilọla Adekọya, ti inagijẹ rẹ n jẹ Princess, lo ṣalaye ninu fọran fidio kan to n ja ranyin lori atẹ ayelujara pẹlu omi loju pe ọdọ oun ni iṣẹlẹ naa ti waye, o ni ọmọbinrin toun gba ṣọmọ lati ọjọ pipẹ sẹyin ni Baba Ijẹṣa ki mọlẹ, to ṣe baṣubaṣu.

Ninu fidio tobinrin naa fi sori atẹ ayelujara insitagiraamu rẹ, o ṣalaye hulẹhulẹ ọrọ naa bayii pe:

“Mo ti gbọ, mo si ti ka gbogbo ohun tawọn eeyan n sọ nipa iṣẹlẹ yii, mi o tiẹ gbadura pe kiru ohun to ṣẹlẹ si mi yii ṣẹlẹ sẹnikan.

“Lọdun diẹ sẹyin, mo lawọn idojukọ kan ninu igbeyawo mi, ọmọ mi ku, ọfọ nla lo si jẹ fun mi, lawọn obi kan laduugbo mi ba ṣeto pe kawọn ọmọ wọn maa waa gbe ọdọ mi, ki wọn le rẹ mi lẹkun, ki wọn maa ba mi ṣere. Bi mo ṣe mu wọn bii ọmọ niyẹn, mẹfa ni wọn, ọkunrin mẹta obinrin mẹta.

“Aarin kan ni Baba Ijẹṣa waa ba mi pe oun lawọn iṣoro kan, pe ki n jọwọ, ran oun lọwọ, mo si gba lati hẹẹpu ẹ, emi ni mo sanwo to fi forukọ silẹ fun lẹsinni (lesson) kan ti mo wa fun un, o ṣe idanwo oniwee-mẹwaa nibẹ (GCE), mo si bẹrẹ si i ba a ṣọna bo ṣe wọle si Fasiti Eko, UNILAG.

Nibi tọrọ iwakiwa ẹ ti bẹrẹ ni pe, lọjọ kan, Baba Ijẹṣa tun waa ba mi pe ki n tun ran oun lọwọ si i. Awọn ọmọkunrin mẹta to wa lọdọ mi lawọn fẹẹ lọọ ṣere laduugbo, mo si gba fun wọn, ọmọbinrin kan tẹle wọn lọ. Emi, aunti mi, Baba Ijẹṣa atawọn ọmọbinrin meji to ku la ṣẹ ku sile. Nigba ti aunti mi fẹẹ maa lọ, mo sin wọn jade, mo tilẹkun geeti ile wa, mi o si mọ nnkan to ṣẹlẹ laarin iṣẹju mẹta si mẹrin ki n too pada de.

Lọsẹ to tẹle e, awọn ọga ileewe tọmọbinrin naa n lọ pe mi lori aago, wọn ni ki n waa wo nnkan ti ọmọ mi n ṣe. Wọn lọmọ naa jokoo sori itan akẹkọọ ẹgbẹ ẹ, lo ba n ṣe bakan bakan. Wọn tun pe awọn obi ọmọkunrin naa gan-an, kristẹni ni wọn. Wọn ni boya iṣoro ọmọbinrin naa ki i ṣe oju lasan, ni wọn ba bẹrẹ si i gbadura.

Emi o mọ pe Baba Ijẹṣa ti kilọ fọmọ yẹn pe ko gbọdọ sọ fẹnikan ni, mo ṣaa ri i pe o tun wa sile mi lọjọ keji, lati waa wo o boya ọmọ ti sọrọ tabi ko sọ. Nigba to de, o loun ra awọn eeso kan wa fawọn ọmọ, o ni kọmọbinrin yii tẹle oun lọ sidii mọto toun gbe wa, aṣe niṣe ni Baba Ijẹṣa lọọ ki kọkọrọ mọto bọ ọmọọlọmọ nidii ninu ọkọ rẹ.

Lẹyin iyẹn, ko wa sile mi mọ, igbakigba to ba nilo iranlọwọ mi, o maa n pe mi lori aago ni, iyẹn lo fi ba mi lọkan jẹ nigba tawọn kan n sọ pe lati ọdun meje sẹyin ni Baba Ijẹṣa ti n fipa ba ọmọ ọhun lo pọ, iyẹn ki i ṣe ootọ rara.

O daa, o ti ṣeṣekuṣe to fẹẹ ṣe, ko si wa sile wa mọ, igba kan to pe mi pe ki n tun ran oun lọwọ, pe oun n ya fiimu kan lọwọ, mo ni ko yẹ ko jẹ emi ti mo fẹẹ ran an lọwọ ni mo maa wa a lọ, ṣugbọn mọ lọ si lokeṣan to loun wa, mo kan kiyesi i pe nigba ti mo de’bẹ, niṣe lo n sa fun mi, o n dọgbọn yẹ mi silẹ, ara ba bẹrẹ si i fu mi, mo n ro o pe ‘ki lo le fa a’.

Ohun mi-in ni pe iṣẹlẹ naa ti nipa lori ọmọbinrin naa. O bẹrẹ si i feeli nileewe, mo ni lati fi i si lẹsinni kan. Mo sọ akiyesi mi fawọn eeyan mi atawọn obi ọmọ ọhun, gbogbo wọn si gba pe kọmọ naa ṣi wa lọdọ mi, wọn ni ka maa gbadura fun un.

Ni bayii, awọn ọmọ naa ti dagba, inu ọgba ileewe (Boarding House), ni wọn n gbe. Mo waa wo o pe ile maa da bi awọn ọmọ yii ba ti tun pada lọ sileewe, emi nikan lo maa ku. Iyẹni ni mo ṣe pinnu lati lọọ gba ọmọ tọ nile awọn ọmọ alainiyaa, ti emi pẹlu rẹ yoo jọ maa wa ninu ile ti Korona ba kasẹ nilẹ. Eyi ni mo n ro lọwọ, ọmọbinrin naa si wa lọdọ mi, lọjọ kan temi ati ọrẹ mi atoun naa, ta a n wo fiimu kan lọwọ, emi ati Baba Ijẹṣa wa ninu fiimu yẹn, bọmọ yii ṣe ri Baba Ijẹṣa lo poṣe, o si dide laarin wa. Ẹnu ya emi atọrẹ mi, la ba lọọ ba a, igba to pẹ ti a ti n beere ohun to ṣẹlẹ, lọmọ ba jẹwọ gbogbo ohun ti Baba Ijẹṣa ti ṣe.

Emi atọrẹ mi pinnu lati wadii ootọ ọrọ lẹnu Baba Ijẹṣa, mo pe e lori aago ẹ, ṣugbọn ko wọle, ni mo ba fọrọ ranṣẹ si i lori instagiraamu ẹ, mo sọ fun un pe mo fẹẹ ya fiimu tuntun kan, mo si fẹ ko kopa ninu ẹ. Bẹẹ niṣe lemi ati mama mi fẹẹ bi i leere ọrọ o.

Awọn eeyan gba mi nimọran pe ki n jẹ kọrọ mi lẹrii, ka ma mu un nigunpaa, ka mu un lọrun ọwọ, eyi lo mu ki n pe ileeṣẹ to n ta kamẹra aṣofofo CCTV, kan, wọn si waa ba mi ṣeto ẹ, ọjọ to loun maa wa naa la fi CCTV sibẹ, koda Baba Ijẹṣa ba awọn oṣiṣẹ ti wọn waa fi kamẹra aṣofofo naa sibẹ, o si beere lọwọ mi nipa wọn, mo purọ fun un pe awọn ti wọn waa tun ẹrọ DSTV mi ṣe ni.

Nigba tawọn yẹn n lọ, mo tẹle wọn, mo sọ fun Baba Ijẹṣa pe mo n bọ, a ti sọ fọmọbinrin yẹn tẹlẹ pe oun ati Baba Ijẹṣa maa wa nile o, a o ni i pẹẹ pada, koda mi o mu foonu mi jade. Ọmọ loun o le da nikan wa nile pẹlu Baba Ijẹṣa, ṣugbọn a sọ fun un pe ko ma wọri, ko le si nnkan kan.

Ba a ṣe jade la ti n wo gbogbo ohun to n ṣẹlẹ nile latori foonu mi-in. Gbogbo inu ile mi ni Baba Ijẹṣa yẹ wo patapata. A ri i bo ṣe n yẹ awọn ile wo boya eeyan ṣi wa nile abi ko sẹnikan. O tun wo ibi ti kamẹra naa wa pẹlu, a o mọ boya o kiyesi i tabi bẹẹ kọ.

Mi o le maa sọ awọn nnkan to ṣe tori a n mọnitọ ẹ ni, ṣugbọn nigba ta a ri i pe o dide lati lọ si yara idana (kiṣinni), ta a si mọ pe ko si kamẹra aṣofofo nibẹ, a tete dari sile, a si pe ọlọpaa ba a ṣe n bọ. Awọn ọlọpaa mu un, wọn si bi i leere pe ki lo fa ohun to ṣe, niṣe lo bẹrẹ si i kilolo, to n ṣe ‘ẹm, ẹm, ẹm.’

“O dun mi pe awọn eeyan kan n beere pe afi tawọn ba ri fọran fidio naa, mo si n ṣe kayeefi pe kin nidii, ki ni wọn fẹẹ fiyẹn ṣe. Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii wọn, Baba Ijẹṣa si ti jẹwọ, ẹẹmẹrin ọtọọtọ lo sọ pe loootọ ni. Kin ni mo fẹẹ purọ mọ ọn fun? Ẹni ti mo ti n ran lọwọ bọ fun ọpọ ọdun, kin ni mo fẹẹ fi iṣubu ẹ ṣe?”

Bayii ni Princess ṣe ṣalaye hulẹhulẹ ọrọ naa ninu fidio oniṣẹju-mẹrindinlogun to fi sori atẹ ayelujara ẹ. Gbogbo eeyan lo si n reti ibi tọrọ yii maa ja si gbẹyin.

Leave a Reply