Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Diẹ lo ku ki rogbodiyan bẹ silẹ niluu Akungba Akoko, nipinlẹ Ondo, lẹyin ti ọmọ Yahoo kan fi ọkọ ayọkẹlẹ rẹ tẹ eeyan mẹta pa laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe iwakuwa ti ọmọ Yahoo ọhun n wa ọkọ lọjọ yii lo mu ko lọọ kọ lu awọn mẹta kan nibi ti wọn duro si, ti meji ninu awọn to ku naa si jẹ ọmọ iya kan naa.
Kete ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn lawọn ọdọ kan tinu n bi ti ko ara wọn jọ, ti wọn si fi ibinu dana sun ọkọ ayọkẹlẹ naa kawọn agbofinro too de bẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin, Alukoro fun ẹgbẹ awọn ọdọ kan nipinlẹ Ondo, Christopher Olusa, ni nnkan ẹdun ati ibanujẹ nla ni ijamba to waye ọhun jẹ fun awọn.
O ni awọn ọna to gba ilu Akungba Akoko kọja n fẹ amojuto gidi lati ọdọ ijọba nitori ọpọ awọn akẹkọọ ti wọn n kẹkọọ ni Fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu ọhun.