̀̀̀̀Ọmọyẹle Ṣoworẹ koju ija sawọn ọlọpaa l’Abuja

Ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni Ọmọyẹle Ṣoworẹ atawọn ọlọpaa koju ija sira wọn niwaju ọfiisi ọga wọn patapata l’Abuja, ti wọn si jọ fa wahala rẹpẹtẹ.

Bi oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters yii ṣe n sun mọ awọn ọlọpaa to duro gangan-an gan, lo n pariwo pe orukọ oun ni Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ti awọn tọhun naa si bi i pe ki lo n wa, ta lo fẹẹ ri, idahun to si fun wọn ni pe, “Ọga ọlọpaa ni mo waa ba.”

Awọn ọlọpaa to wa lọfiisi yii ko si dakẹ ariwo ti wọn n pa mọ ọn pe ko pada, oni ni Satide, to ba di Mọnde, ọjọ Aje, ko pada wa.

Ni Ọmọyẹle ba tun bi wọn wi pe ṣe ọga yin ki i wa sibi iṣẹ loni-in Satide ni?

Bi wọn ti ṣe n fa a mọra wọn lọwọ niyẹn ki ọkan ninu awọn ọlọpaa naa too pe e ni ‘ewu’, eyi to tumọ si ewurẹ lede awọn Ibo.

Nibi ti inu ti bi Ṣoworẹ niyẹn, to si fa ibinu yọ gidigidi. Ọkunrin oniroyin yii sọ pe alaimọkan lo pọ ju ninu awọn ọlọpaa ti ko fẹẹ gba oun laaye lati ri ọga wọn yii, nitori iya to n jẹ wọn ko kere.

O fi kun un pe oun mọ bi baraaki wọn ṣe ri daadaa, ati pe igbe aye wọn buru pupọ. O ni ti wọn ko ba dara pọ mọ iwọde ta ko oriṣiiriṣi iwa tijọba n hu yii, Naijiria ko ni i le lọ siwaju rara, bẹẹ lawọn naa yoo maa jiya si i.

Awọn ọlọpaa naa ko gbẹnu wọn dani o, wọn jọ na an tan bii owo ni, ṣugbọn ki Ṣoworẹ too kuro nibẹ, o fi da wọn loju pe oun nikan loun wa loni-in, gbogbo ọdọ Naijiria pata loun n ko bọ lọjọ Aje, Mọnde, ti apa wọn ko ni i le ka a.

Nibi to ti n fibinu sọrọ naa lo ti kọ lu Buhari, to sọ pe nnkan ti daru mọ Aarẹ orilẹ-ede yii lọwọ, bẹẹ ni ko mọ ohun to yẹ ko ṣe mọ.

One thought on “̀̀̀̀Ọmọyẹle Ṣoworẹ koju ija sawọn ọlọpaa l’Abuja

Leave a Reply