Ọpẹ o, awọn OPC ti mu Wakili, Fulani to n da wọn laamu l’Ayetẹ

Sẹnkẹn ni inu awọn eeyan agbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, paapaa ju lọ, awọn ara ilu Ayetẹ, n dun nigba ti iroyin kan wọn lara lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, pe ọwọ ti tẹ ọkan pataki ninu awọn Fulani darandaran to n da awọn eeyan agbegbe Ibarapa, paapaa ju lọ ilu Ayetẹ, nipinlẹ Ọyọ, laamu, iyẹn Wakili.

Aṣeyọri yii ko sẹyin ẹgbẹ OPC ti Aarẹ Gani Adams n dari. Awọn eeyan naa ni wọn tọ ọ lọ ni ibuba rẹ to ti di ẹrujẹjẹ sawọn eeyan ilu naa lọrun, ti ko si si ẹni to too koju ọkunrin alagbara naa.

Yatọ si pe Wakili ni ibọn, awọn eeyan ilu Ayetẹ royin pe oogun buruku wa lọwọ ọkunrin naa. Aya si ko o debii pe gbangba lo ti n sọ ọ fun awọn eeyan pe Sunday Igboho ti awọn eeyan Ibarapa gbọkan le ko to lati koju oun, o ni ki wọn lọọ pe e wa.

Nigba ti wahala awọn Fulani si le ni Ibarapa gidigidi, ti ọrọ di ọlọmọ ko mọ ọmọ, ti ọrọ naa buru debii pe ọkan ninu awọn ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho, lo wa siluu Igangan lati le awọn Fulani naa lọ, niṣe ni Wakili paala si bii abule marun-un, to ta aṣo pupa di ọna ibẹ, to si ni ẹnikẹni ninu awọn eeyan ilu naa to ba fẹẹ ku iku ojiji ni ko gba ibẹ kọja. O ni pipa loun yoo pa ẹnikẹni ti oun ba ri ninu awọn eeyan ilu Ayetẹ to ba kọja awọn ibi ti oun faala si.

Ibẹru yii ni ko jẹ ki awọn eeyan naa debẹ, onikaluku sa fun ori ara rẹ. Bẹẹ ni awọn eeyan naa n duro de igba ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo ko awọn agbofinro wa lati lọọ koju ọkunrin naa, ṣugbọn eyi ko ṣẹlẹ rara.

Awọn ọmọ ẹgbẹ Oodua ti Aarẹ Gani Adams n dari ni wọn wọnu igbo tọ ọkunrin naa lọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti wọn si ka a mọle pẹlu awọn ọmọ rẹ kan, ni wọn ba gbe e janto.

Ki i ṣe pe ojubọrọ naa ni wọn fi gbe e gẹgẹ bi adari awọn OPC naa, Oloye Adedeji Oluwọle, ṣe sọ. Ọkunrin naa ṣalaye pe ibọn ni awọn eeyan Wakili da bolẹ nigba ti awọn debẹ, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn mọ awọn. O ṣalaye pe ọpẹlọpẹ Ọlọrun atawọn alalẹ Oodua ni ko jẹ ki ibọn awọn Wakili ran awọn.

O ni gẹgẹ bi awọn ṣe ṣeleri pe awọn maa mu ọkunrin Fulani to ti sọ ara rẹ di ologomugomu si awọn eeyan Ibarapa lọrun yii lai si itajẹ silẹ kankan, Adedeji ni oun layọ lati sọ pe awọn ti mu ọkunrin to n da wahala silẹ niluu Ayetẹ, to si n fi maaluu jẹ oko awọn eeyan naa lai si ẹni to to lati mu un. Ọba ranṣẹ si i, ko lọ, bẹẹ lawọn ijoye ilu pe e, ko dahun.

Iyalẹnu to wa ninu ọrọ naa ni pe agbalagba ni ọkunrin ti wọn n pe ni Wakili yii, ki i ṣe ọmọde rara. Nigba ti wọn de ibuba rẹ ti wọn mu un, bi wọn ṣe n bi i lọrọ to, niṣe ni ọkunrin naa n ṣe bii ẹni to ti fẹẹ ku, ko da wọn lohun. Sugbọn awọn ọmọ OPC ni niṣe lo n pirọrọ nitori pe awọn ọmọ rẹ sọ pe ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a lo tan yii, lo lọ si orileede Benin, iyẹn ni Kutonu, nibi ti wọn lo ti lọọ gbatọju lori oju to n dun un.

Oloye Oluwọle ni awọn ti n gbe e lọ si ibi ti awọn yoo ti fa a le awọn agbofinro lọwọ.

Leave a Reply