Ọpọlọpọ aṣọ sọja ni wọn ka mọ Tochukwu lọwọ niluu Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ọmọ ibo ti wọn mu niluu Ọrẹ pẹlu ọpọlọpọ aṣọ sọja lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja. Alukoro awọn ọlọpaa niipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Ọdunlami ni awọn agbofinro to n peṣe aabo fawọn araalu loju ọna marosẹ Benin si Ọrẹ ni wọn mu Tochukwu ninu ọkọ Toyota Sienna kan ti nọmba rẹ jẹ UWN 505 ZL.
Igba ti wọn n yẹ inu ọkọ ọhun wo lo ni awọn ba ọpọlọpọ aṣọ, fila pẹlu awọn ohun eelo mi-in to jẹ tawọn ọmọ ologun, eyi to di sinu apo dudu kan to gbe sinu ọkọ rẹ.
O ni aṣọ ologun tuntun mẹwaa, fila mẹsan-an, adamọdi aṣọ mẹjọ ati ohun eelo awọn ọmọ ologun ti wọn fi n daabobo orukun wọn mẹjọ.
O ni ohun ti awakọ ọhun n tẹnu mọ nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo ni pe, ẹnikan lo gbe ẹru naa wa sinu gareeji ti oun ti n gbero niluu Eko, to si ni ki oun ba oun gbe e fun elomi-in nipinlẹ Anambra.
Ọdunlami ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju nitori pe o di dandan ki awọn mọ ẹni to gbe awọn ẹru ofin naa fun Tochukwu, ẹni to fẹẹ lọọ gbe e fun ni Anambra ati ohun ti wọn fẹẹ fi ṣe.


Leave a Reply